Nnkan de o! Wọn ti ji mọto Oluwoo gbe

Olajide Kazeem

Loruganjọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii ni awọn janduku kan ji mọto Hilux Oluwoo ilẹ Iwo, Ọba Abdul-Rasheed Akanbi, gbe niluu Eko.

Agbẹnusọ fun ọba alaye naa, Ọgbẹni Alli Ibraheem lo fi ikede ọhun sita. Ohun to si sọ ni pe otẹẹli kan ti wọn n pe ni Toilam Royal Hotel, lagbegbe Igboṣere, nigboro Eko, ni wọn ti ji mọto ọhun gbe sa lọ.

Ọda funfun ni wọn fi kun un, orukọ Ọba Adewale Akanbi ni wọn kọ sara ẹ gẹgẹ bii ami idanimo ọkọ naa.

2 thoughts on “Nnkan de o! Wọn ti ji mọto Oluwoo gbe

Leave a Reply