Ọṣun 2022: Agbẹjọro agba mẹjọ, lọọya mejidinlaaadọta ni yoo ṣoju Adeleke – Alimi

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ofuutufẹẹtẹ ni ẹjọ ti Gomina Oyetọla ati ẹgbẹ APC pe lati ta ko ijawe olubori gomina tuntun l’Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke. Igbakeji alakoso ipolongo ibo fun ọkunrin naa, lasiko idibo gomina to waye kọja nipinlẹ Ọṣun, Barisita Kọla Alimi, lo sọ bẹẹ.

Alimi ṣalaye pe agbẹjọro agba (SAN) mẹjọ ati awọn agbẹjọro mejidinlaaadọta ni awọn olujẹjọ mẹtẹẹta, iyẹn ajọ eleto idibo INEC, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ati ẹgbẹ oṣelu PDP gba lati yanju gbogbo ohun ti ẹgbẹ APC ko jọ.

A oo ranti pe ibo to le ni ẹgbẹrun mejidinlọgbọn ni Adeleke fi fi ẹyin Oyetọla balẹ ninu idibo gomina ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii.

Lẹyin naa ni Oyetọla ati ẹgbẹ APC wọ Adeleke, ajọ INEC ati ẹgbẹ PDP lọ sile-ẹjọ to n gbọ ẹsun to ṣu yọ lẹyin idibo (Tribunal)

Ibudo idibo to din diẹ ni ọtalelẹẹẹdẹgbẹrin (749) ni Oyetọla gbe lọ si kootu, lara awọn nnkan to n sọ ni pe adiju ibo wa ni awọn ibudo idibo naa. O n beere pe ki ajọ eleto idibo fagi le esi idibo agbegbe naa, ki ajọ eleto idibo si gba satifikeeti ọwọ Adeleke fun oun.

Amọ ṣa, Alimi ṣalaye pe digbi lawọn wa, ko si si mimi kan to le mi awọn, ati pe awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ni wọn finu-findọ dibo fun Sẹnetọ Ademọla Adeleke lasiko idibo to kọja.

Leave a Reply