Ọṣinbajo, Tinubu, Arẹgbẹṣọla, Omiṣore atawọn agbaagba Yoruba wọle ipade l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko
Titi di asiko ti a n kọ iroyin yii lọwọ ni ipade ṣi n lọ laarin awọn ọmọ Yoriba ti wọn fẹẹ dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ninu ibo aarẹ ọdun to n bọ atawọn agbaagba oloṣelu ọmọ Yoruba mi-in.
Awọn agbaagba ilẹ Yoruba kan la gbọ pe wọn pe ipade naa lati fẹnu ọrọ jona lori bi wọn yoo ṣe fagba fẹnikan lori ipo naa, ti Yoruba ko fi ni i le eku meji ki wọn padanu ọkan.
Lara awọn ti wọn ti wa nibi ipade ọhun ni Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, Alagba Bisi Akande, Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi, Gomina ipinlẹ Ondo ati ti Ọsun, Rotimi Akeredolu ati Adegboyega Oyetọla. Gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ, Ibikunle Amosun, Gomina ipinlẹ Ogun bayii, Dapọ Abiọdun. Bakan naa ni Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba ati gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Rauf Arẹgbẹṣọla. Bẹẹ ni Akọwe ẹgbẹ APC bayii, Iyiọla Omiṣore, gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Niyi Adebayọ ati Babajide Raji Faṣọla.
ALAROYE gbọ pe mọto kan naa lo gbe Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ati gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Rauf Arẹgbẹṣọla, wa sibi ipade naa.
A oo tun maa fi bo ṣe n lọ to yin leti

Leave a Reply