O ṣẹlẹ, Ijọba Buhari fi SWAT rọpo SARS

Ọga ọlọpaa ilẹ wa, Muhammad Adamu, ti gbe ẹka ileesẹ ti yoo maa mojuto iwa ọdaran mi-in dide lati rọpo SARS. SWAT lo pe orukọ wọn, iyẹn (Special Weapon and Tactics Team).

Ọsẹ to n bọ lo ni wọn yoo bẹrẹ iṣẹ lẹyin ti wọn ba ti ṣe ayẹwo finni finni fun wọn lati ri i pe ọpọlọ wọn jipepe, wọn si kun oju  osunwon lati ṣiṣẹ naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa lapapọ, Frank Mba, lo sọ eyi di mimọ niluu Abuja lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii. O fi kun un pe gbogbo awọn ọlọpaa to ti wa ni ẹka  SARS ni wọn gbọdọ yọju si ileesẹ ọlọpaa niluu Abuja fun ayewo ọpọlọ wọn lati ri i pe wọn wa ni ipo to daa, ki wọn too ko wọn pada sinu iṣẹ ọlọpaa pada.

4 thoughts on “O ṣẹlẹ, Ijọba Buhari fi SWAT rọpo SARS

 1. Nise ni oro swart ti won sese da sile yi dabi oro ijoba Apc ati Pdp ole gbe ole gba sebi awon ti e paro oruko won kuro ni sars naa letun gba sinu swart Olorun a gba wa kuro lowo ijoba ti o bikita isofo emi ati dukia yi o.

 2. Janba nta fun janba ra!
  Omo iya laja ohun Obo,
  Omo iya ni Elede ohun imado,
  Okanjua ohun Ole deede loje!!
  Obon ohun asiwere okanhun-kanhun…..Sio!! Swat ko,suwaati niii..

 3. Oloriburuku ni ijoba to wa nita lasiko yio sebi awon to n wuwa buruku yan na ni won tun Yi oruko won pada se iwa owo won le Yi pada ni? Ero temi ni wipe ki orile ede yi mo lo leyo kokan. Nitori Nigeria yi koni ife awon ara inu re. Ti awa ara ilu ba so wipe ao fe nkankan ko ye ki ijoba tun mo kun nkan oun loda fun wa mo. Ero temi eje ki ada orile ede tiwa Sile ki enu wa le ka ara WA.

Leave a Reply