O ṣelẹ, orileede Nijee fofin de ọkọ ofurufu eyikeyii lati Naijiria!

Faith Adebọla

Owe a ki i kere nidii nnkan ẹni, ati pe ba a ti ṣe laa wi, lo wọ ọrọ ija abẹnu to n lọ laarin awọn alaṣẹ orileede Niger ati ti Naijiria lasiko yii, amọ ọrọ ọhun ti bọna mi-in yọ, awọn ṣọja to n ṣakoso lorileede Nijee ti kọwe si Aarẹ Bọla Tinubu pe lati asiko yii lọ, awọn o fẹẹ ri ọkọ baaluu eyikeyii lati Naijiria, awọn si ti wọgi le gbogbo irinajo ọkọ ofurufu to n lọ lati Nijee si Naijiria, tabi eyi to fẹẹ wa lati Naijiria si Nijee.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ to n ṣakoso irinajo oju ofurufu lorileede naa, eyi ti wọn pe ni NOTAM, eyi ti wọn kọ lọjọ kẹfa, oṣu Keji, ọdun 2024 yii ni wọn ti kede pe:

“Oju ofurufu orileede Niger wa ni ṣiṣi silẹ fun gbogbo irinajo ofurufu lorileede yii atawọn orileede agbaye gbogbo, ayafi orileede Nigeria, ko saaye fun baaluu lati fo lati ọdọ wa lọ sibẹ, tabi lati Nigeria wa sibi.

“Ifofinde yii ko kan awọn baaluu elero to n lọ lati orileede kan si omi-in, to fo kọja ni Naijiria, amọ ti ko balẹ nibẹ.

“Lọwọ keji ẹwẹ, ofin ta a fi de awọn baaluu ologun ati awọn baaluu fun iṣẹ akanṣe lati orileede eyikeyii ṣi wa sibẹ, ko ti i yipada. Bi baaluu ologun tabi akanṣe kan ba fẹẹ balẹ sorileede wa, wọn gbọdọ kọkọ gba iyọnda awọn alaṣẹ ṣaaju ki wọn too gbera.”

Bayii lawọn alaṣẹ naa sọ.

Ẹ oo ranti pe ṣaaju asiko yii ni ijọba Naijiria ti kọkọ fofin de irinajo ofurufu lati orileede Naijiria si Nijee, tabi lati Nijee wa si Naijiria.

Wọn ni gbedeke yii wa lara ipinnu ti ajọ awọn orileede Iwọ-Oorun ilẹ Afrika, Economic Community of West African States, (ECOWAS), eyi ti Tinubu jẹ Alaga wọn fẹnu ko le lori, latari bawọn ṣọja ṣe doju ijọba dẹmokiresi de lorileede naa, ti wọn fipa gbajọba, ti wọn ko si ṣetan lati sọrẹnda.

Orileede Nijee wa lara awọn orileede mẹta ti wọn kede laipẹ yii pe awọn o ṣe ajọ ECOWAS mọ, wọn ni kaka ki kiniun ṣakapo ẹkun, koowa yoo wulẹ ṣe ọdẹ rẹ lọtọọtọ ni.

Leave a Reply