O ma ṣe o, eeyan mẹsan-an ku ninu ijamba ọkọ l’Ekiti

Taofeek  Surdiq, Ado-Ekiti

Beeyan ba jẹ ori ahun, poro-poro lomije yoo maa da loju rẹ bo ba debi ijamba mọto kan to ṣẹlẹ ni ilu Ijan-Ekiti, ni kututu aaro ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii. Niṣe ni wọn to oku awọn eeyan naa silẹ bẹẹrẹbẹ, ti agbara ẹjẹ si n ṣan bii omi, ninu ijamba mọto to ṣẹlẹ loju ọna to lọ lati ilu Ado-Ekiti si Ijan/Ilumọba-Ekiti.

Boosi akero alawọ funfun kan to ko ero mejidinlogun, ti  nọmba idanimọ rẹ jẹ ONDO KER 44 XA, to gbera lati ilu Ado-Ekiti  to n lọ si Ikarẹ, nipinlẹ Ondo. O ri afara nla kan to kọja ilu Ijan-Ekiti, ko too de Ilumọba-Ekiti lo wa to fi fẹẹ ya ọkọ ajagbe nla  kan silẹ, lasiko to fẹẹ ṣe eleyii lo sadeede la ori mọ ọkọ akero miiran ti nọmba idanima tiẹ jẹ  LAGOS  APP 207, to oun naa n bọ lati ilu Ikare, to n lọ si ilu Ado-Ekiti.

Awọn ara ilu Ijan-Ekiti to wa nibi iṣẹlẹ naa to ba ALAROYE sọrọ sọ pe lojiji ni ọkọ akero yii fẹẹ ya ọkọ ajagbe yii silẹ ni kete to kọja ori afara yii, lojiji ni ọkọ miiran sare yọ loju popo naa, eleyii to fa a ti ọkọ akero yii fi fa ori pada sinu, ṣugbọn aṣọ ko ba Ọmọye mọ, bo ṣe fẹẹ fa ori pada sinu lo la ori mọ ọkọ akero bọọsi miiran to n bọ lati ilu Ikare.

Eleyii lo fa a ti mẹsan-an lara awon ero to wa ninu ọkọ naa ṣe jẹ Ọlọrun ni ipe lojiji, nigba ti awọn mejilelogun miiran fi ara pa yanna-yanna.

Ni akoko ti a fi n ko iroyin yii jọ awọn ọlọpaa ati awọn ẹsọ ojupopo ti wa ni ibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, ti akitiyan si n lọ lọwọ lati ko awọn oku ati awọn to fara pa nibi iṣẹlẹ naa lọ si ileewosan.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe oun wa nibi ti iṣẹlẹ  naa ti ṣẹlẹ lakooko toun fi n ba ALAROYE sọrọ, o juwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii ohun to buru gbaa, o rọ gbogbo awakọ ki wọn maa ni suuru loju popo nigbakigba ti wọn ba n wa ọkọ.

Leave a Reply