O ma ṣe o! Wọn ge ọwọ ọmọ ile-kewu lọ ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni wọn ge ọwọ ọmọdekunrin kan ti ko ju ọmọ ọdun meje lọ, Usman Abubakar, to jẹ ọmọ ile-kewu lọ niluu Patigi, ijọba ibilẹ Patigi, ipinlẹ Kwara.

Abubakar jẹ ọmọ ilẹ kewu Mallam Aliyu Adamu to wa ni ilu naa.

Agbẹnusọ ajọ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnṣi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afọlabi, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ni awọn ti gbọ pe arakunrin kan lọ si ilu Patigi pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ, to si gbe Abubakar to jẹ ọmọ ile- kewu pẹlu awọn meji miiran, to si ni oun fẹẹ lọọ gbe ounjẹ fun wọn, sugbọn inu igbo lo gbe wọn lọ, to si ge ọwọ ọmọdekunrin naa, sugbọn awọn meji to ku mori bọ lọwọ ọdaju ọkunrin ọhun.

Afọlabi tẹsiwaju pe okunrin ọhun ti mu ọwọ naa lọ, ti Abubakar si wa ninu agbara ẹjẹ. Ṣugbọn wọn ti gbe e lọ si Ọsibitu Jẹnẹra to wa ni Patigi lati doola ẹmi ọmọdekunrin ọhun. O waa fi kun un pe awọn ti fi ẹsọ alaabo sọwọ si ilu naa lati ṣawari awọn amookun ṣika yii.

Leave a Reply