Ọdalẹ ni Fẹmi Adeṣina, a maa wo ibi ti yoo foju si ti Buhari ba lọ-Afẹnifẹre

Lọjọ Satide, ọjọ kẹwaa, oṣu keje yii, Olori ẹgbẹ Afẹnifẹre, Oloye Ayọ Adebanjọ, sọrọ kan nipa Fẹmi Adeṣina to jẹ oludamọran pataki fun Aarẹ Muhammadu Buhari lori eto iroyin. Baba sọ pe ọdalẹ ni Fẹmi Adeṣina, o lo ti dalẹ iran Yoruba patapata.

Ninu ifọrọwerọ kan ti Olori Afẹnifẹre naa ṣe pẹlu iwe iroyin Daily Independent lo ti sọ pe bi a ba wo ọrọ ti Fẹmi sọ laipẹ yii, nibi to ti n ṣegbe lẹyin Buhari, to n sọ pe o daa bo ṣe n fọwọ lile mu ẹnikẹni to ba lodi sijọba rẹ, eeyan yoo ri i pe iwa ọdalẹ paraku ni.

Oloye Adebanjọ fi kun alaye naa pe iwa ẹni ti ko ni i pada sawujọ Yoruba mọ lẹ́yìn ijọba Buhari ni Fẹmi Adeṣina n hu, o ni Fẹmi ko ranti pe ọba mẹwaa, igba mẹwaa, lọrọ ile aye yii, ẹnikan ki i lo ile aye gbo.

Baba Adebanjọ sọ pe, ” Latigba ti Fẹmi Adeṣina ti gbaṣẹ oniroyin lọdọ Buhari ni iṣe rẹ ti yatọ sohun to maa n kọ sinu iwe iroyin ‘The Sun’ nigba to n se olootu iwe naa.

‘Fẹmi ti ta ara ẹ faraata laarin Yoruba, o ti dalẹ wa. Niṣe lo ro pe irọ ni yoo leke otitọ, bẹ́ẹ̀, otito lo n leke irọ lọjọ gbogbo.

‘Adeṣina ti gbagbe pe Buhari yoo fipo aarẹ silẹ lọjọ kan, Naijiria yoo si duro ni tiẹ, ko nibi kan ti yoo lọ. Nigba naa la oo wo Adeṣina, ta oo beere lọwọ rẹ pe ‘Nibo lo wa bayii o ‘

Baba Adebanjọ kadii ọrọ rẹ nilẹ pẹlu ileri pe Naijiria yoo ṣẹgun Buhari pẹlu adura, Buhari yoo lọ nilẹ yii, a o waa maa wo baye Fẹmi Adeṣina yoo ṣe ri nigba yẹn.

Leave a Reply