Ohun ti Ọbasanjọ o le ṣe, ti Jonathan o le ṣe, wọn ni Buhari ti ṣe e o

Aderounmu Kazeem

Bo tilẹ je pe ariwo bi epo pẹtirioolu ṣe tun lewo si i yii wa nigboro, tawọn oṣiṣẹ ṣi n leri wi pe awọn yoo daṣẹ sile, sibe, ileeṣẹ Aarẹ ti sọ pe, gbogbo ọmọ Nigeria ṣi n pada bọ waa yin Muhammed Buhari nigbẹyin, ti wọn yoo si maa ṣadura fun un to ba ya.

Arojare ni agbẹnusọ fun ileeṣẹ Aarẹ, Ọgbẹni Garba Shehu, ki si bayii, ohun kan naa to si tẹnu mọ ni pe, pupọ ohun ti awọn ijọba to ti rekọja lọ kuna lati ṣe ni Aarẹ Buhari n ṣe bayii, paapaa bijọba ẹ ṣe gbe igbesẹ lati yọwọ patapata ninu owo iranwọ tijọba n na lori epo bẹntiroolu.

Ninu ọrọ e lo ti sọ pe, “Awọn Ijọba to kogba sile (bii ti Ọbasanjo ati Jonathan) ki Aarẹ Muhammed Buhari to bọ sori ipo paapaa ti sọ ọ tele wi pe ọna kan pato ti Nigeria fi le nilọsiwaju ni ki ijọba dawọ ipese owo iranwọ lori epo duro, ati pe eyi gan-an ni yoo fopin si ṣiṣe owo ilu makumaku. Ṣugbọn wọn fẹnu sọ bẹẹ lasan ni, wọn ko le ṣe e. Oun na ani Buhari si ṣe.”

Bo tilẹ jẹ pe awijare ti Garba Shehu ṣe ree, sibẹ ọkunrin yii kuna lati bojuwo iha tawọn alatako kọ si igbesẹ yii wi pe ki i ṣe iru asiko yii ti gbogbo aye n kigbe irora ati inira airowona, airi nnkan jẹ, lo ye kijọba yọwọ patapata.

Tẹ o ba gbagbe, lọdun 2015 ni eto idibo nla kan waye ni Nigeria, ẹgbẹ oṣelu APC ni Aarẹ Muhammed Buhari gbe kalẹ lodun naa, o si jọ pe gbogbo ọmọ Nigeria pata lo ṣetan lati tẹle ọkunrin aloku ṣọja yii. Ki oloju si too ṣẹ ẹ, ẹgbẹ oṣelu naa lo wọle o, ti wọn si fi ẹyin ẹgbẹ oṣelu PDP janlẹ gidigidi.

Ijọba Buhari to wọle lọdun yẹn ko ṣai mu ọpọ eeyan maa woye wi pe, pupọ ninu ohun to ti doku ni Nigeria ni ọkunrin yii yoo ji, nitori wọn ri i bii olootọ eeyan, ti iwa ibajẹ yoo si wa sopin ni Nigeria.

Ero nla ti awọn ọmọ Nigeria ni ree o, ṣugbọn nigba ti ohun gbogbo bẹrẹ si ri bo ṣe ri loni-in, ẹkun lẹlomi-in ko le bu si, bo tilẹ jẹ pe niṣe lawọn kan sunkun ọhun gidigidi, ti wọn si n sọ ọ laarin ara wọn pe, nnkan de o, aye ko rẹrin-in rara mọ ni Nigeria.

Bi owo epo pẹtiroolu ṣe tun gbowo lori bayii, ti owo tawọn eeyan tun n san fun ina ijọba tun wọn si, ti ounjẹ paapaa ko ṣe ra mọ lọja, ti owo mọto naa di ohun nla fawọn eeyan lati maa san tabi ri, eyi gan-an lo mu won maa kerora gidi, ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ si sọ pe, o di dandan, ki awọn daṣẹ silẹ.

Bi eyi ti ṣe n lọ lọwọ, nni ileeṣẹ Aarẹ naa ti fọrọ kan sita, ohun ti Mallam Garba Shehu, ẹni ti ṣe agbẹnusọ fun Aarẹ si sọ ni pe, pẹlu igbesẹ akin ti Aarẹ Muhammed Buhari gbe yii lori bo ṣe yọwọ kuro ninu owo iranwọ lori epo ati ina ijọba, niṣe lawọn ọmọ Nigeria yoo pada yin in, ti gbogbo aye yoo si ri i pe, oore nla lo waa ṣe fun wa.

O fi kun ọrọ ẹ wi pe, “Lati le fopin si bi wọn ṣe n na owo to yẹ ki ijọba fi ṣe araalu lanfaani, iyẹn gan-an lo mu ijọba gbe igbesẹ yii. Gbogbo iwa ajẹbanu to n ṣẹlẹ lori owo epo, owo tijọba n na lori ina ọba, ati eto iranwọ ti ijọba n ṣe lori ipese ajilẹ atawọn ohun meremere mi-in, asiko ti to bayii lati yọwọ, eyi ti yoo fun ijọba lanfaani lati ṣeto ati ilana to peye, ti eto karakata yoo si wa ni ibamu pẹlu iye ti ọja ba ba de ati iye ti wọn gbọdọ ta a”

O ni, “Bo tilẹ jẹ pe gbogbo awọn to ti ṣakoso orilẹ-ede yii nigba kan ri ni wọn mọ, ṣugbọn ko si eyikeyi ninu wọn to ni igboya lati ṣe e, ṣugbọn ni bayii ti Aarẹ Muhammed Buhari ti gbe igbesẹ yii, gbogbo ọmọ Nigeria naa ni wọn yoo yin in to ba ya, nitori oore nla nigbesẹ naa yoo jẹ fun gbogbo ọmọ Nigeria.”

 

Leave a Reply