Ohunkohun ko le da ipade apapọ ẹgbẹ PDP duro lọjọ Satide yii-Okowa

Faith Adebọla

 Pẹlu bawọn kan ṣe ko ọkan soke lori idajọ ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ti wọn lo maa waye l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, lori ipade apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Gomina ipinlẹ Delta, Ifeanyi Okowa, ti fọwọ sọya pe mimi kan ko le mi apero naa, o ni dandan ni ko waye lọjọ Satide yii tawọn ṣeto ẹ si.

Ilu Abuja, ni olu-ile ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, lọkunrin naa ti sọrọ yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, o ni gbogbo ẹjọ wuruwuru to wa nilẹ laarin ẹgbẹ PDP apapọ lawọn ti yiri ẹ wo lọkọọkan, awọn si ti gbe igbesẹ lati pa oju ẹjọ de lawọn kootu ti wọn wa.

Okowa, to jẹ Alaga igbimọ to n sami sawọn to maa pesẹ sibi ipade apapọ naa lọjọ Satide sọ pe ko dun mọ awọn ninu bi iwe ipẹjọ ṣe n fo wọle lọtun-un losi ninu ẹgbẹ PDP, awọn si ti gbe igbesẹ to yẹ nipa ẹ.

“Gbogbo awọn ẹsun wọnyi la ti gbe yẹwo, titi kan bawọn kan ṣe fẹẹ gbegi dina fawọn aṣoju to fẹẹ wa sibi apejọ naa.

Ṣugbọn ere ori igi ni, aṣeku ọmọ ẹdun ni, a ti n boju to o, to ba fi maa di Ọjọbọ, Tọsidee, gbogbo orukọ ati eto nipa awọn to maa wa si ipade naa yoo ti pari. Ma a sọ iye awọn to maa pesẹ fun yin laaarọ ọjọ Furaidee.

Ni ti ẹjọ to wa ni kootu, mimi kan o mi wa, ọkan wa balẹ lori ẹ, iti ọgẹdẹ ni, ko to nnkan ti a n lọ ada si, a maa pari ẹ, Ọlọrun wa pẹlu wa.

Ṣe ẹ ri i pe eyi to pọ ju lọ ninu awọn ipo wọnyi ni ko si alatako fun, ondije kan naa ni.

A mọ pe ti ko ba ti siṣoro nipa awọn to n bọ, ko le siṣoro nipade naa, ko si le siṣoro lasiko idibo awọn oloye ẹgbẹ,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Tọsidee nile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun sọ pe oun yoo gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ ti Alaga PDP tawọn kan fẹẹ le danu, Ọmọọba Uche Secondus, pe, o bẹ kootu naa pe ko paṣẹ tako ipade to n bọ naa, pe ki wọn ṣi jawọ ninu ẹ na. Bi Ifa rẹ yoo fọ’re lọla tabi bẹẹ kọ lẹnikan ko ti i le sọ.

Leave a Reply