Ọlọpaa ṣi n wa awọn apaniṣowo to ge ori iya arugbo lọ n’’Ikun-Ekiti

Taofeek Surdiq,Ado-Ekiti

Inu ibẹru-bojo lawọn eeyan ilu Ikun-Ekiti, nijọba ibilẹ Mọba, wa bayii pẹlu bi wọn ṣe ṣadeede ji sita l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ti wọn ba oku iya arugbo kan ti wọn ti ge ori re lọ.

Iya ẹni ọdun mẹrinlelọgọrin naa torukọ rẹ n jẹ Ayọdele Ashaolu, lo n da nikan gbe inu ile alamọ kan to jẹ ile ojule mẹrin. Ibẹ ni awọn janduku kan ti wọn ko ti i mọ lọọ ka a mọ, ti wọn si ge ori rẹ, ti wọn gbe e lọ, wọn si di iyoku ara rẹ sinu apo, wọn gbe  e pamọ si kọrọ igun ile naa.

Iku iya to jẹ pe oun lo dagba ju niluu naa jẹ ohun to ya gbogbo eeyan lẹnu.

Ẹnikan to n gbe ilu naa ṣalaye fun akọroyin wa ọmọkunrin kekere kan to lọọ ra nnkan nile to wa lẹgbẹẹ ile iya arugbo yii laaarọ Ọjọbọ yii lo ri i, to si kigbe pe awọn araadugbo.

Iku iya arugbo yii ti da ọfọ ati ibanuje silẹ niluu naa pẹlu bawọn eeyan ilu naa ṣe n wọ lọ si ile oloogbe yii lati wo oku iya arugbo naa ninu ile to n gbe.

A gbọ pe mọlẹbi atawọn eeyan ilu naa ti bẹrẹ itọpinpin ati iwadii lati mọ awọn to ṣiṣẹ buruku naa.

Lara awọn eeyan ilu naa sọ pe ohun to ṣee ṣe ko fa iku iya yii ni bi oun atawọn mọlẹbi rẹ atawọn ara ilu naa ṣe n ja lori ẹni ti yoo gba owo ‘gba ma binu’ lori ilẹ mọlẹbi naa ti awọn ileeṣẹ aladaani kan ti wọn fẹ maa ṣe miliiki fẹẹ san fawọn mọlẹbi naa.

Ẹlomiran ni ilu naa ṣalaye pe o le jẹ pe awọn ọdọ kan ni ilu naa lo ge ori iya arugbo yii lati fi ṣe oogun owo, eyi ti wọn ni o wọpọ lagbegbe naa.

Leave a Reply