Faith Adebọla, EkoỌpẹlọpẹ awọn ọlọpaa ti wọn tete de ibi iṣẹlẹ ọhun, boya ori iso ni Ọgbẹni Reuben iba dakẹ si, latari bi ọkunrin olowo kan, Oluchi Okoye tawọn eeyan mọ si Paka (Packer), ṣe so o mọlẹ bii ẹran ti wọn fẹẹ pa, o lo jẹ oun ni gbese, oun o si ni i tu u silẹ titi to fi maa san gbese ẹ.
Iṣẹlẹ yii waye lọjọ Ẹti, Furaidee yii, l’Ojule kọkandinlọgbọn, Opopona Abẹokuta, lagbegbe Ebute-Mẹta, nipinlẹ Eko, ibẹ ni Ọgbẹni Paka n gbe.
Ba a ṣe gbọ, wọn ni loootọ ni Reuben Alozie jẹ Paka lowo, owo naa si pọ tori owo ele ni, gbese ọhun ti ju miliọnu mẹrin aabọ naira (N4.6m), lọ.
Paka ṣalaye fawọn ọlọpaa pe gbogbo ọna loun ti ṣan pe ki onigbese yii le san owo oun foun, o loun tiẹ fun un lanfaani lati maa sanwo naa diẹ diẹ, ṣugbọn aroye ni onigbese naa maa n ṣe foun lojoojumọ.
O loun ti fẹjọ ẹ sun awọn mọlẹbi ẹ titi, sibẹ oun o gbọ pa, oun o gbọ po lori ọrọ naa, igba to su oun loun fawọn eeyan dọdẹ rẹ, tori o ti bu ọna ile oun diwọ, ki i jẹ si adugbo naa mọ, nigba ti olobo si ta oun ni Tọsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu yii, pe awọn kan kofiri Reuben, loun ba lọ mu un.
Bi Paka ṣe wọ Reuben de agbala ile rẹ, ko ṣe meni ṣe meji, niṣe lo sọ ọkunrin naa di ẹran ti wọn n ta ni Kara, o fokun de e lọwọ ati ẹsẹ mọ awọn igi ti wọn ri mọlẹ lẹyinkule ile naa ni, inu ebutu nibẹ lo so o mọlẹ si, o lo digba toun ba ri owo oun ko too kuro lori iso.
Bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko ṣe wi, Adekunle Ajiṣebutu ni ori iso ni Reuben wa tilẹ fi mọ, ti ilẹ ọjọ keji tun fi n ṣu lọ, kawọn alaaanu kan ti wọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa too sọ fun iyawo Reuben to ti n daamu pe oun o ri ọkọ oun latana, niyawo naa ba lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa.
Awọn ọlọpaa teṣan Denton, lagbegbe Ebute-Mẹta, ni wọn sare debi iṣẹlẹ ọhun, wọn ba Reuben to n ṣẹju pako lori iso to wa, wọn lẹmii ti fẹẹ bọ lẹnu ẹ, wọn si ri olowo rẹ naa to n leri pe dandan loun maa gbowo oun, lawọn ọlọpaa ba tu ọkunrin naa silẹ, ọkan lara wọn lo pọn ọn bii ọmọ ikoko, ti wọn fi sare gbe e lọ sileewosan fun itọju, wọn si fi pampẹ ofin gbe Mista Paka, to sọ eeyan ẹgbẹ ẹ di ewurẹ ori iso tori owo.
Ṣe eebu alọ ni t’awun, abọ ni t’ana ẹ, ọpọ awọn aladuugbo tọrọ naa ṣoju wọn ni wọn koro oju siwa ti Paka hu yii, niṣe lawọn eeyan n ṣepe fun un pe ọdaju, alailaaanu ati apaayan ni.
Ṣa, wọn ti taari ẹ sọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n bojuto iwa ọdaran abẹle ni Panti, Yaba, fun iwadii to lọọrin lori iṣẹlẹ naa, ki wọn too mọ igbesẹ to kan.