Ọpẹyẹmi ni Pasitọ Samuel rẹ oun jẹ, lo ba ji i gbe ninu ṣọọṣi rẹ

Gbenga Amos, Abẹokuta

Iwa bi adiẹ ba da mi loogun nu, emi naa aa fọ ọ lẹyin lo waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Keje yii, nigba tawọn gende meji ti wọn wọṣọ ṣọja, ati obinrin to tẹle wọn, Ọpẹyẹmi Ibikunle, ja wọnu ṣọọṣi ZOE Family International Church, to wa laduugbo Odo Ẹran, ni Lafẹnwa, niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, wọn ji Pasitọ ti n ṣewaasu lọwọ ninu ṣọọṣi naa, Samuel Mapai, gbe, ṣugbọn obinrin to ṣeto ijinigbe naa, ti jẹwọ fawọn ọlọpaa pe oun da sẹria fun pasitọ ni o, tori o rẹ oun jẹ ninu okoowo tawọn jọ ṣe.

Nnkan bii aago mẹjọ alẹ niṣẹlẹ ọjọ Wẹsidee, ọhun niṣẹlẹ naa waye, ijọsin alẹ ni wọn n ṣe lọwọ, ojiji lawọn ṣọja naa bẹ gija wọnu ṣọọṣi, ọdọ pasitọ yii ni wọn lọ taara, wọn si fipa wọ ọ jade sinu ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn gbe wa, ko sẹni to mọbi ti wọn gba, tori ibẹrubojo ti mu gbogbo awọn olujọsin yooku, niṣe ni wọn doju bolẹ pẹlu ijaya.

Gẹrẹ ti wọn lọ tan ni awọn kan ninu ṣọọṣi naa fi iṣẹlẹ ọhun to ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Arẹgba leti, kia si ni DPO ẹka naa, CSP Gabriel Ikechukwu, ti forikori pẹlu awọn ọtẹlẹmuyẹ to wa pẹlu ẹ, wọn bẹrẹ si i fimu finlẹ.

Wọn ni ko ju wakati mẹta lẹyin naa ti awọn afurasi ajinigbe naa fi pe ẹnikan lori aago lati sọ fun wọn pe ọdọ awọn ni Pasitọ Samuel wa, ki wọn tete lọọ wa owo rẹpẹtẹ wa lati gba a silẹ, aijẹ bẹẹ, ẹlẹkọ ọrun ti n polowo fun un.

Awọn ọtẹlẹmuyẹ ṣayẹwo finni-finni si ipe yii, iwadii wọn ati imọ ijinlẹ jẹ ki wọn ri i pe ayika Abẹokuta lawọn to ṣiṣẹ laabi yii wa, wọn si bẹrẹ si i tọpasẹ wọn, titi ti aṣiri fi tu pe inu igbo kan nitosi Adigbẹẹ, l’Abẹokuta, ni wọn wa, lawọn ọlọpaa ba ya bo wọn.

Meji ninu wọn ti wọn wọṣọ ṣọja sa lọ, ṣugbọn ọwọ tẹ Ọpẹyẹmi ati Jamiu Kadiri. Ni tọlọpaa, Ọpẹyẹmi ṣalaye pe oun loun wa nidii iṣẹlẹ naa, o lo ti pẹ toun ati pasitọ ti mọra, awọn si jọ n ṣe okoowo kan, ṣugbọn niṣe ni pasitọ naa lu oun ni jibiti nidii okoowo ọhun, nigba ti aṣiri iwa abosi to hu tu soun lọwọ loun fi pinnu lati fiya jẹ ẹ, eyi lo mu ki oun pe awọn mẹta yooku lati ba oun ji i gbe, koun le kọ ọ lọgbọn gidi.

DSP Oyeyẹmi Abimbọla, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, to fọrọ yii to ALAROYE leti sọ pe Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti paṣẹ pe ki wọn taari Ọpẹyẹmi ati Jamiu sọdọ awọn aṣofintoto ki wọn le tubọ ṣewadii wọn daadaa, iṣẹ si n lọ lati mu awọn meji ti wọn sa lọ.

 

Leave a Reply