Ọpọ eeyan ko jade dibo ijọba ibilẹ nipinlẹ Ogun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ko sija, ko si jagidijagan, ṣugbọn ko si awọn oludibo to bẹẹ ju bẹẹ lọ pẹlu, iyẹn nibi eto idibo sawọn ijọba ibilẹ to waye nipinlẹ Ogun lọjọ Satide, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje, ọdun 2021.

Ni Aarin-Gbungbun Ogun, Iwọ-Oorun ati Ila-Oorun, awọn oludibo to jade ko to nnkan rara, bẹẹ, awọn eeyan forukọ silẹ, ṣugbọn lọjọ idibo yii, awọn to jade dibo kere gidi.

Lori idi ti eyi fi ri bẹẹ, Dokita Abdullahi Mohammed Jabi, to sọrọ lorukọ ẹgbẹ ‘Civil Society Organisation’, ṣalaye pe akọkọ ni pe ẹru n ba awọn eeyan, nitori ko si aabo laarin ilu.

O ni ikeji ni pe inu awọn eeyan ko dun, ara ko si ya wọn sijọba yii nitori ọrọ aje to n bajẹ, ti gbogbo ọja n gbowo leri lojoojumọ, ti ko si tun sowo ti wọn yoo fi ra a, titi kan ohun jijẹ ti ko ṣee ma ni.

Dokita Jabi sọ pe loootọ nijọba ipinlẹ Ogun pese aabo to peye ṣaaju idibo yii, to jẹ gbogbo awọn ẹṣọ alaabo lo duro wamu, o ni inu didun lo n mori ya, ẹni ti inu rẹ ko dun, ti ko rowo na ko le ronu ibo didi, nitori yoo maa ro o pe eyi toun ti n di latẹyin wa, ki lo ba de.

Ṣa, Gomina Dapọ Abiọdun ṣapejuwe ibo naa bii eyi to lọ nirọwọ-rọsẹ, ti ko mu wahala dani, ti awọn eeyan si jade ṣe ojuṣe wọn.

O gboriyin fun ajọ OGSIEC to ṣeto ibo naa, o ni wọn ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ lohun gbogbo ṣe lọ bo ṣe yẹ.

Aago mejla ọsan ku iṣẹju mẹtadinlogun ni Gomina Dapọ Abiọdun de si Wọọdu kẹta, n’Ipẹru, Uniiti keji lo ti dibo, n’Ita  Ọsanyin, Ipẹru Rẹmọ.

Nipa awọn ẹka PDP ti wọn lawọn ko ni i kopa ninu idibo naa, Gomina Abiọdun sọ fawon akọroyin pe oun ko mọ nnkan kan nipa ẹ.

O ni o ṣee ṣe ko jẹ abala ti kootu ko da mọ lo ṣe ipinnu iru rẹ, o ni ṣugbọn nigba ti oun ki i ṣe lọọya, toun ko si ki i ṣe OGSIEC, ko si boun yoo ṣe le sọ ohunkohun nipa awọn ti wọn lawọn ko ni i kopa.

 

Leave a Reply