Ori ko awọn oṣiṣẹ panapana yọ lọwọ iku ojiji ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, lori ko awọn oṣiṣẹ ajọ panapana nipinlẹ Kwara yọ lọwọ iku ojiji nigba ti tanka agbepo kan gbina lẹgbẹẹ ileepo Ibrosalam, lọna mọrosẹ Bode-Saadu, nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara.

Agbẹnusọ ajọ naa nipinlẹ Kwara, Hassan Hakeem Adekunle, sọ pe tanka epo kan lo takiti si ẹba ọna tepo-tepo, ti ajọ panapana si fẹẹ lọọ doola ijamba ọhun, lasiko ti wọn de ibi iṣẹlẹ naa ni tanka epo ọhun sadeede gbina, ṣugbọn ori ko awọn oṣiṣẹ naa yọ lọwọ iku ojiji. O di ẹbi iṣẹlẹ naa ru dẹrẹba agbepo ọhun tori pe ẹru to gbe ti pọ ju, o si tun n sare asapajude.

Adari ajọ panapana nipinlẹ Kwara, Ọmọọba Falade John Olumuyiwa, ti gba awọn dẹrẹba ọkọ agbepo nimọran lati maa din ere sisa wọn ku, ki wọn si ma ko ẹru to ju ọkọ lọ mọ lojuna ati dena ijamba oju popo to n ṣẹlẹ lemọ-lemọ.

Leave a Reply