Orile Igboro kanjangbọn lọwọ awọn Fulani, wọn pa wọn tọmọtọmọ

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Orile-Igboro, ilu kan ti awọn eeyan ibẹ ko foju kan oorun lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu keji, ọdun 2021. Ba a si ṣe n kọroyin yii, ibẹ ko ti i fara rọ latari ibẹru to ṣi wa lọkan awọn eeyan, leyin ti awọn Fulani wọle tọ wọn lọwọ alẹ, ti wọn ṣa wọn ladaa tọmọtọmọ, ti wọn si yin awọn mi-in nibọn pa.

Ilẹ Ketu ni ilu yii wa, ni Yewa. Awọn agbegbe bii Egua, Ijoun ati Ọja Ọdan ko jinna sibẹ. Beeyan ba kọja ibi kan ti wọn n pe ni Iyana-Mẹta. Ikọlu to si ti waye nibẹ latọwọ awọn Fulani tawọn eeyan naa fẹẹ le kuro nibẹ ko kere rara.

Lati alẹ ọjọ Jimọ ti ikọlu yii waye lawọn eeyan ti n kede ẹ lawọn oju opo ayelujara, pe awọn Fulani ti ya bo Orile-Igboro o, wọn ti n pa awọn eeyan, wọn n dana sunle, wọn si n ṣa awọn ọmọde paapaa ladaa, bẹẹ ni ko si iranlọwọ kankan fawọn eeyan naa. Ko si agbofinro kankan nitosi, ko tilẹ si kinni kan to jẹ iranwọ, awọn eeyan naa ko sọwọ awọn Fulani to n gbẹsan ẹṣẹ ti wọn ko ṣẹ lara wọn ni.

Nigba tilẹ yoo fi mọ, aworan awọn ti wọn wọle pa, awọn ti wọn ṣa ladaa atawọn ti wọn yin nibọn lo gba ori afẹfẹ, bẹẹ ni awọn eeyan n sọrọ abuku sijọba ipinlẹ Ogun lori ayelujara, wọn ni wọn ti kawọ gbera ju, wọn ko ṣe nnkan kan si ohun to n ṣẹlẹ yii, bẹẹ, bi ogun yoo ba ṣẹlẹ, bo ti n kọkọ ri naa ree, ibẹrẹ ogun leeyan n mọ, o loju ẹni ti i ri ipari ogun.

Nibi ti ọrọ ọhun le de, ALAROYE gbọ pe wọn ti gbe Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Awolọlọwọ Ajogun, lọ sipinlẹ Plateau bayii. Jos ni wọn ni wọn gbe e lọ, bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i kede ẹni ti yoo rọpo rẹ nipinlẹ Ogun.

Ẹ oo ranti pe ninu ọsẹ yii kan naa ni awọn Fulani paayan meji ni Owode-Ketu, bo tilẹ jẹ pe meji to foju han niyẹn ni, to jẹ eeyan mẹfa lawọn mi-in ti wọn jẹ olugbe ibẹ sọ pe wọn ku, bẹẹ awọn Fulani lo ṣigun lọọ ba wọn lọsan-an gangan. Niṣe ni wọn ti awọn ileewe ati ọna aje wọn gbogbo pa, nigba ti ilu ko toro, to jẹ kaluku n wa ọna ti yoo fi sa kuro nile ki wọn ma baa ba ogun ọsan gangan naa lọ ni.

Ẹ oo ranti pe bawọn Fulani ṣe n daamu awọn eeyan ilẹ Yewa yii lo mu Sunday Igboho, ajijagbara ọmọ Yoruba nni, wa si ipinlẹ Ogun yii, apẹyinda wiwa naa lo di bawọn Fulani ṣe bẹrẹ si i koju awọn ọmọ oniluu bayii, ti wọn n kọju ija si wọn tọsan-toru.

Ohun to n pa ọpọ eeyan lẹkun lori iṣẹlẹ yii ni pe ijọba ji giri sọrọ awọn to fẹẹ ṣewọde pe ki wọn ma ṣi Too-geeti Lekki, l’Ekoo, wọn ko ọlọpaa lọ sibẹ biba, wọn si n mu awọn ti wọn n ṣewọde wọọrọwọ lai lo nnkan ija kankan. Ṣugbọn ko sẹnikan to ji giri si ipaniyan to n ṣẹlẹ nipinlẹ Ogun, wọn ko mu Fulani kan bayii latigba ti ipaniyan ti n waye, awọn eeyan si n padanu ẹmi, wọn n padanu dukia wọn.

ALAROYE gbiyanju lati ba aṣofin to n ṣoju ẹkun Yewa keji nile-igbimọ aṣofin Ogun, iyẹn Ọnarebu Wahab Haruna Egungbohun, sọrọ, niṣe ni nọmba rẹ n wa lori ipe mi-in titi, atẹjiṣẹ ta a si fi ṣọwọ si i pẹlu, ko ti i fesi rẹ ta a fi pari iroyin yii.

 Ṣugbọn ẹka iroyin oloyinbo kan ti wọn ni ọkunrin naa ba awọn sọrọ, sọ pe Egungbohun fidi ẹ mulẹ pe eeyan mẹrin lawọn ti ri oku wọn laaarọ ọjọ Satide ti i ṣe ọjọ keji ikọlu yii, ati pe awọn to ṣeṣe pọ, awọn ti wọn si n wa naa wa nibẹ pẹlu.

Ṣa, ohun tawọn eeyan yii n rawọ ẹbẹ sijọba si latigba ti wahala yii ti n ṣẹlẹ ni pe ki wọn bawọn kapa awọn Fulani yii, ki wọn le wọn lọ tefetefe, ki wọn wa ibomi-in ti wọn yoo ti maa fẹran jẹko fun wọn.

Leave a Reply