Ọrọ Bọla ati Yẹmi: Ta lọdalẹ! (1)

Mo ri ohun to ṣẹlẹ nigba ti Yẹmi kede fun gbogbo aye pe oun fẹẹ du ipo aarẹ. Ere buruku ni Bọla (Tinubu) sa nibi yoowu to wa, nigba ti oloju si fi maa ṣẹju, Bọla ti wa l’Abuja, wọn lo n ṣepade pẹlu awọn gomina APC, loootọ lo si jokoo saarin wọn. Awọn ọmọlẹyin rẹ, ati awọn digbolugi ti wọn haaya sori ẹrọ ayelujara ti bẹrẹ si i bu Yẹmi, orukọ kan naa ti wọn si n pe e ni ọdalẹ, wọn lo dalẹ Bọla ni, nitori Bọla lo kọ ọ niṣẹ, oun lo fi i mọna, oun lo ṣe ohun gbogbo fun un. Ẹrin ni mo bẹre si i rin, nitori mo mọ pe ogede alaimọkan pọ pupọ ninu awọn ti wọn n gbe iru ọrọ bẹẹ kiri. Ati Bọla o, atawọn ọmọlẹyin ẹ, ohun ti mo ri ninu wọn ni ijaya nla! Pe Yẹmi jade lati kede pe oun fẹẹ du ipo aarẹ, ojiji lo ba awọn araabi yii, o kan wọn kuu, nitori wọn ti n gbe ara wọn gun ẹṣin aayan pe Yẹmi ko laya, ko jẹ jade.
Nigba ti Yẹmi waa jade bayii, niṣe ni ede gbogbo wọn daru, omi-in si fẹrẹ le pokunso ninu wọn. Ni wọn ba bẹrẹ si i sare kiri, Bọla funra ẹ sare fara han l’Abuja, o n wa awọn gomina kiri, ohun to si fẹẹ ṣe ni lati ri kinni kan to maa gbe iroyin nipa oun naa jade, ti iru iroyin bẹẹ fi maa bo ohun to ṣẹlẹ ni kutukutu owurọ naa mọlẹ, ti awọn eeyan ko fi ni i sọrọ Yẹmi to jade mọ. Bi oun ti n sare palọ ninu yara yii, bẹẹ lawọn ọmọ ẹ bẹrẹ ariwo. Wọn bẹrẹ ariwo ta a wi yii, ariwo to si gba ẹnu wọn ju naa ni ariwo ọdalẹ: “Ọdalẹ l’Ọṣinbajo”, ohun kan naa ti wọn n ri sọ niyẹn. Bẹẹ aimọkan ni o! Ẹni ba mọkan, to dakan mọ, to ba mọ ohun ti wọn n pe ni aye, to mọ ohun ti wọn n pe ni oṣelu, ko ni i sọ iru ọrọ bẹẹ rara, nitori ohun to wa nisalẹ ọrọ le ju ohun tawọn araata n ri, tabi ohun tawọn ti wọn ba n tẹle oloṣelu kan le mọ lọ.

Bi a ba n sọrọ, tabi ti a ba darukọ ọdalẹ ninu oṣelu ilẹ Yoruba, ẹni to yẹ ki wọn pe ni ọdalẹ gan-an ni Bọla. Nilẹ Yoruba yii, ninu awọn oloṣelu to bẹrẹ lati ọdun 1998 titi di asiko ti a wa yii, ko si ọdalẹ kan to ju Bọla lọ. Ni gbangba ni mo ti n sọ ọ yii, mo si ni awọn ẹri to daju ni. Ni 1998, Fẹmi (Ojudu) to wa lẹyin Yẹmi bayii lo n mu Bọla kiri ile awọn agbaagba, nitori oun ṣe eto ninu kampeeni ẹ, ko si agba kan ninu Afẹnifẹre, tabi AD, ti Bọla ko lọọ ba. Nibẹrẹ eto oṣelu igba naa, Wahab Dosumu lawọn agba ti kọkọ sọ pe oun lawọn fẹẹ fa kalẹ fun ipo gomina Eko. Bọla yii ti mọ bẹẹ, nitori ẹ lo jẹ nigba to de, sẹnetọ Eko lo fẹẹ lọọ ṣe l’Abuja, o ni inu oun aa dun ti a ba le foun ni tikẹeti sẹnetọ. Ohun ti wọn n ṣeto ẹ fun un niyẹn, pe ko lọ sileegbimọ aṣofin agba.
Ọlọrun lo waa mọ ohun to gbe fun Ẹgbọn Gani (Ganiyu Dawodu), niyẹn ba bẹrẹ si i tẹle e kiri ile awọn agbaagba yii, to n sọ fun wọn pe Bọla lo daa ko ṣe gomina, ọmọde ni, aa tọju gbogbo awọn bi awọn ba fi i ṣe e. Ẹgbọn yii ni alaga ẹgbẹ AD ti ipinlẹ Eko, ọwọ ẹ si ni gbogbo agbara ẹgbẹ naa wa l’Ekoo. Bi Ẹgbọn Gani ṣe yẹju awọn Dosumu, ti wọn ni ki oun lọọ ṣe Sẹnetọ, ti wọn le Kofo Akerele Bucknor sẹyin, ti wọn ni obinrin loun, igbakeji ni ko ṣe, ti wọn ti gbogbo wọn si ẹgbẹẹgbẹ nitori Bọla niyẹn. Eyi ti a ṣaa maa ri ni pe Bọla lẹgbẹ AD fa kalẹ. Ọrọ naa sọ Funṣọ Williams to ti nawo nara gan-an fawọn Afẹnifẹre di ọta wọn, nitori Ẹgbọn Gani ati Baba Adebanjọ ni wọn mọ bi wọn ṣe fi Bọla ṣe gomina Eko. Bi Bọla ṣe di gomina, Ẹgbọn yẹn ati Baba ni, Afẹnifẹre ni wọn si lo fun un. Oju awa yii lo ṣe, ki i ṣe ẹyin wa.
Nigba ti wọn mu Bọla tan, ko si owo lọwọ ẹ lati fi ṣeto idibo, awọn eeyan ti wọn yi i ka ni wọn n wa owo kiri fun un. Ile Gbenga (Daniel) to wa ni Maryland, nibẹ ni Bọla jokoo, ti wọn si ṣe gbogbo eto naa to fi wọle. Nibo ni Ẹgbọn Gani ko sare de fun un, ọna wo ni wọn ko fi ran an lọwọ lati di gomina. Awọn eeyan yii gan-an ni ipilẹ Bọla ni Eko yii, awọn ni wọn fi i jẹ gomina, awọn ni wọn fun un ni gbogbo agbara. Bi ko si tiwọn, ninu oṣelu Eko igba naa, ta ni iba mọ Bọla, meloo meloo awọn ti wọn jọ de lati Oke-Okun nigba naa ti ko sẹni to gburoo wọn mọ, ti wọn ko si ri ipo oṣelu gidi kan di mu nigba ti wọn de. Bi Bọla ba jẹ kinni kan tawọn ọmọ ẹyin ẹ n pariwo lonii yii, awọn ti wọn jẹ ko jẹ nnkan kan, awọn ti wọn fẹyin pọn ọn, awọn ti wọn ṣiṣẹ silẹ fun un to waa jẹ, awọn aṣaaju Afẹnifẹre ni. Bẹẹ ni ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ wọn ko too lọ, igba to de lo ṣẹṣẹ darapọ mọ wọn.
Ṣugbọn nigba ti Bọla di gomina, ki lo ṣẹlẹ o! Bọla ti ka awọn oriṣiiriṣii iwe, awọn iwe buruku to n kọ ẹni ti wọn ba fi jọba ilu, tabi ti wọn ba fi sipo agbara, pe awọn to gbọdọ kọkọ doju ija kọ ni awọn to fi i joye, nitori bi ko ba ṣe bẹẹ, wọn ko ni i jẹ ko gbadun ijọba ẹ. Ohun ti Bọla ṣe niyẹn. Ija ati ọtẹ naa le debii pe gbogbo awọn agbaagba yii n beere lọwọ ara wọn pe ṣe Bọla ti awọn mọ naa ree ṣa. Ohun to faja ko ju pe ko ma na owo Eko ni inakunaa lọ, ko jẹ ki awọn tọ ọ si ọna lori ohun to le ṣe. Bọla yari mọ wọn lọwọ, o ko awọn ọmọ ẹ, awọn ti wọn waa jọ n ja loni-in yii o, awọn Raufu (Arẹgbẹṣọla), Lai (Muhammed), Dele (Alake) atawọn ẹgbẹ wọn ti wọn n ba a ṣiṣẹ nigba naa, o ko wọn sodi, wọn bẹrẹ si i ba Ẹgbọn Gani ja, wọn ba a ja titi ti wọn fi le e kuro ninu AD, ti iyẹn fi binu lọọ da PAC silẹ.

Nigba ti asiko ibo to, Ẹgbọn Gani yii ko lowo lọwọ, PAC ko si le wọle nibi kan l’Ekoo, nitori Bọla ri owo Eko na. O gba ẹgbẹ naa lọwọ wọn debii pe ati awọn baba Afẹnifẹre o, ati awọn ọga ẹ tẹlẹ o, gbogbo wọn lo le kuro ninu ẹgbẹ naa. Ko too di asiko ibo rara lo ti le Iya yẹn, Kofo Akerele lọ, o loun lo n lọọ sọ aṣiri oun fawọn baba Afẹnifẹre. Nigba ti wọn wọle lẹẹkeji ti ijọba Eko waa bọ si i lọwọ, nigba naa lo fọkan balẹ, to wa n ṣe bo ṣe wu u, ṣe o ti le gbogbo awọn ti wọn da ẹgbẹ silẹ kuro lọdọ ẹ, kidaa awọn ọmọọṣẹ ẹ lo ku, awọn ti wọn le ku nitori rẹ. Asiko naa ni owo de lojiji, owo kan ko si de lojiji naa ju owo Eko yii naa lọ, owo Eko ni, ko si ariyanjiyan ninu ẹ. Tabi bawo ni ẹni ti ko lowo nigba to fẹẹ du ipo ni 1998 ṣe waa di olowo aye lojiji, owo ijọba ni, owo Eko ni!
Nitori ẹ ni ẹnu ṣe maa n ya mi nigba ti awọn ti wọn n tẹle e loni-in ba n sọrọ ọdalẹ, tabi wọn n wi ohun ti ko ye wọn. Ta ni ọdalẹ! Ki lo de ti awọn ko lo laakaye pe awọn ti wọn gbe Bọla sipo da, bawo lo ṣe ṣe wọn ki Eko too di tirẹ! Awọn ti wọn fi ori laku fun un, awọn bii Arẹgbẹ, bii Dele, ati awọn ogunlọgọ to ti lo pa ti, ki lo de ti awọn n ba a ja. Abi awọn ti wọn n pariwo lori ẹrọ ayelujara yii mọ Bọla bii Arẹgbẹ! Eeyan kan le mọ Bọla ninu awọn ti wọn n pariwo yii bii Dele ni. Tabi eeyan le mọ ọn bii Afikuyọmi! Ṣebi awọn to lo to n fi wọn dẹruba gbogbo awọn agbaagba ree. Ṣebi awọn lo lo to fi gba gbogbo ilẹ Eko, owo ati dukia ati awọn ohun Eko gbogbo niyi! Ki lo de ti awọn ti wọn n sọrọ ọdalẹ lonii ko beere pe ki lo faja oun ati awọn eeyan yii, ki wọn si gbẹnu ṣọhun-un, ki wọn yee sọ ohun ti wọn ko mọ rara.
Ki lo ṣẹlẹ laarin oun ati Yẹmi gan-an. Bo ba di ọsẹ to n bọ, ma a sọ fun yin.

Leave a Reply