Faith Adebọla
Minisita feto igbokegbodo ọkọ, Rotimi Amaechi, ti gbeja ijọba to wa lode yii lori iṣoro eto aabo to dẹnu kọlẹ lorileede yii, o ni ki i ṣe ẹbi Aarẹ Muhammadu Buhari rara, ki i si i ṣe ẹbi ẹgbẹ oṣelu APC, o lawọn to ti ṣakoso ki APC too de ni wọn fa iṣoro ọhun.
Amaechi ni ko tọna rara lati sọ pe ijọba to wa lode yii lo fa awọn janduku agbebọn ti wọn ṣọṣẹ kaakiri, o lawọn ti wọn ti ṣolori sẹyin la gbọdọ dẹbi ru, tori awọn ni wọn ṣe ohun alumọọni orileede yii baṣubaṣu tẹlẹ.
Lọjọ Ẹti, Furaidee yii, nigba to n sọrọ nibi ti wọn ti n ṣi ofiisi tuntun ti wọn kọ fun ajọ awọn to n kẹru gba ori omi (Nigerian Shippers Council), ẹka ti Aarin-Gbungbun Ariwa, niluu Jos, nipinlẹ Plateau, lo sọrọ ọhun.
O ni ọkan lara idi tawọn fi n ṣi ọfiisi tuntun naa ni lati din iwa janduku, ifẹmiṣofo ati iṣoro aisi aabo ku, tori ti ko ba si iṣẹ fawọn eeyan, iwa ọdaran ko le dinku.
O ni: “Idi ti iwa ọdaran fi wa ni pe awọn olowo ti wọn tukọ ọrọ-aje orileede yii sẹyin fọpọlọpọ ọdun, niṣe ni wọn ṣe e baṣubaṣu. Emi o mọ idi tawọn ọmọ Naijiria fi n sọrọ bii ẹni pe ijọba tiwa yii ni akọkọ.
Ki awa too de, ṣebi awọn ijọba kan ti wa. To ba jẹ pe wọn bojuto ọrọ-aje daadaa, ti wọn si da iṣẹ silẹ ni, a o ni i maa sọrọ aabo to mẹhẹ ati iwa awọn janduku agbebọn lasiko yii. Mo maa n sọ ọ lọpọ igba fawọn eeyan pe tawọn ọlọrọ ko ba jẹ kawọn mẹkunnu ri oorun sun wọra, awọn mẹkunnu naa o ni i jẹ kawọn naa sun asun-han-an-run rara. Gbogbo wa la jọ maa laju silẹ ta a o maa ba ara wa ja.
Amaechi ni owe amukun-un ti ẹru rẹ wọ ni ọrọ Naijiria yii, atilẹ ni ẹru naa ti wọ wa, ki i ṣe ọrọ ijọba to wa lori aleefa yii.