Ọwọ aṣọbode tẹ awọn oniṣowo fayawọ, wọn gbẹsẹ le ọja olowo nla

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọwọ ileeṣẹ aṣọbode nilẹ yii, Nigeria Customs, ẹka tipinlẹ Ọyọ ati Ọṣun ti tẹ ọkunrin oniṣowo kan nibi to ti n ṣe fayawọ awọn ọja ti ijọba fofin de.

Gbogbo ọja ti ko gbọna ojugbo wọle pata ni wọn gba lọwọ ẹ. Ọna aadọta (50) ni wọn lo di awọn ẹru naa si.

Ninu awọn ẹru ọhun la ti ri ẹgbẹrun mẹta o le nigba (3,200) apo irẹsi, awọn bata pẹlu aṣọ loriṣiiriṣii, ọpọlọpọ kẹẹgi ororo atawọn nnkan mi-in.

Nigba to n ba awọn oniroyin soro lolu ileeṣẹ wọn  to wa laduugbo Agodi, n’Ibadan, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii. Ọga aṣọbode ẹka yii, Ọgbẹni Adamu Ramat Abdulkadir, sọ pe owo ti ko din ni biliọnu mẹẹẹdogun naira lajọ naa pa sapo ijọba apapọ ilẹ yii laarin oṣu mẹfa akọkọ ọdun 2021 yii.

Ọgbeni Abdulkadri ṣalaye pe, ṣaaju asiko yii lọwọ awọn ti tẹ awọn afurasi meji kan, ti awọn si ti foju wọn ba ile-ẹjọ.

Leave a Reply