Ọwọ ẹsọ Amọtẹkun tẹ awọn Fulani bii aadọta to ya wọ Okitipupa loru

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ.

Ọgọọrọ awọn Fulani darandaran kan ti wọn deedee ya bo Okitipupa, nijọba ibilẹ Okitipupa, lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ ta a lo tan yii lo ti da jinnijinni bo awọn eeyan ilu ọhun.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, awọn bororo to n lọ si bii aadọta ni wọn fi okunkun boju wọ inu ilu ọhun pẹlu ọpọlọpọ maaluu ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ naa.

Bi wọn ti de itosi bareke awọn ologun to wa loju ọna abawọlẹ si aarin igboro Okitipupa lawọn araalu kan ti jade pẹlu igboya ti wọn si fipa da ọkọ wọn duro fun ọpọlọpọ wakati ki awọn ẹsọ Amọtẹkun ti wọn ti sare pe too waa ba wọn.

Diẹ ninu awọn Fulani ọhun la gbọ pe wọn bẹ silẹ ninu ọkọ lasiko ti wọn n ko wọn pada lọ si Akurẹ to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo, ti wọn si ṣe bẹẹ sa mọ awọn ẹsọ Amọtẹkun lọwọ.

Awọn bii marundinlaaadọta ni wọn ri ko de olu ileeṣẹ awọn Amọtẹkun to wa l’Akurẹ, nibi ti wọn si wa ni gbogbo asiko ta a fi n kọ iroyin yii lọwọ.

Araalu kan to ba wa sọrọ sọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn ẹsọ alaabo ti fi panpẹ ofin gbe pupọ ninu awọn darandaran ọhun, ọkan awọn eeyan ko ti i balẹ síbẹ̀ latari awọn to raaye sa mọ wọn lọwọ nigba ti wọn n ko wọn lọ.

Oloye Adetunji Adelẹyẹ to jẹ alakooso agba fun ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju lori rẹ.

Alaga ijọba ibilẹ Okitipupa, Ọnọrebu Igbẹkẹle Akinrinwa, ṣalaye pe iwadii ti fihan pe ẹnikan to jẹ ọmọ oniluu lo ṣatọna bawọn bororo ohun ṣe raaye wọle siluu.

O ni kawọn eeyan lọọ fọkan balẹ, nitori pe ojuṣe ijọba ni lati peṣe aabo to yẹ fun ẹmi ati dukia araalu.

Leave a Reply