Ọwọ tẹ adigunjale mẹwaa ati Idris to n ṣe baba isalẹ wọn n’Ikẹja

Faith Adebọla, Eko

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ni awọn ti tun iṣẹ to, awọn ti n gbọna ọtun yọ sawọn ọdaran ti wọn n yọ ipinlẹ naa lẹnu, o si jọ pe igbesẹ naa meso jade pẹlu bọwọ ṣe ba awọn ọmọkunrin mẹwaa loju popo ti wọn ti n ja awọn onimọto at’ero lole.

ALAROYE gbọ pe nnkan bii aago meji ọsan ọjọ Aiku, ọjọ ki-in-ni, oṣu karun-un yii, ni olobo ta awọn ọlọpaa pe awọn adigunjale n jale lọwọ lagbegbe Ikẹja, lawọn ikọ ọlọpaa ti wọn pe ni Strike Team ba lọọ gbena woju wọn, tọwọ si ba mẹwaa lara wọn.

Orukọ awọn ti wọn fi pampẹ ofin gbe naa ni Sadiq Masaki, ẹni ọdun mejilelogun, Ọladimeji Ọlatunbọsun, ẹni ọdun mẹrinlelogun, Adam Hassan, ẹni ọdun mọkanlelogun, Tunde Afọlayan, ẹni ọdun mẹrinlelogun, ati Michael Ademọla, ẹni ọdun mejilelogun.

Awọn marun-un to ku ni Ọlamide Johnson, ẹni ogun ọdun, Abiọdun Ọpẹyẹmi, ẹni ọdun mejilelogun, Oluṣeyi Agbaje, ẹni ọdun mọkanlelogun, Daniel Ayọmide, ẹni ogun ọdun ati Adebayọ Tobi, ẹni ọdun mọkanlelogun.

Alukoro ọlọpaa, Olumuyiwa Adejọbi, to fọrọ yii ṣọwọ si wa lọjọ Aje, Mọnde, sọ pe oriṣiiriṣii ada ati ibọn meji lawọn ba lọwọ awọn apamọlẹkun ẹda yii. Wọn ni oogun abẹnu gọngọ ati egboogi oloro ti wọn fura pe igbo ni, tun wa lapo wọn.

Lati Ikẹja tọwọ ti ba wọn ni wọn ti taari wọn si ẹka awọn ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, fun iwadii. Lẹnu iwadii naa laṣiiri ti tu pe baba agbalagba ẹni ọdun mejilelogoji kan ti wọn porukọ ẹ ni Idris Adamu lo n ṣe baba isalẹ fawọn kọlọransi ẹda wọnyi, wọn loun lo n ba wọn wa oogun, oun naa lo si n gba ẹru ti wọn ba ji gbe, oun lo n ṣeto tita ati pinpin owo ti wọn ba pa.

Agbegbe ọja Alade Market, ni Ikẹja, ni baba naa n gbe, awọn ọlọpaa si ti lọọ mu un. Wọn lawọn ba foonu rẹpẹtẹ ninu ile ọkunrin naa, wọn ba awọn ibọn agbelẹrọ, ṣeeni, olowo nla, aago atawọn dukia mi-in loriṣiiriṣii.

Kọmiṣanna ọlọpaa, Hakeem Odumoṣu, ni awọn maa foju awọn ọdaran naa bale-ẹjọ laipẹ, awọn o si ni i kaaarẹ lati mu awọn alaigbọran to taku sidii iwa ọdaran nipinlẹ Eko.

Leave a Reply