Ọwọ ti tẹ ọkan ninu awọn ajinigbe to yinbọn pa awakọ l’Akunnu Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn eeyan fẹrẹ tẹ ara wọn pa nibi ti wọn ti n gbiyanju, ti wọn si n jijadu lati wo afurasi kan tọwọ tẹ lori iku Oloogbe Toyin Mala, ìyẹn awakọ to n na Ajọwa si Abuja ti awọn agbebọn kan pa l’Agọọ Jinadu, lagbegbe Akunnu, lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, yatọ si pe ọrẹ timọtimọ ni afurasi tọwọ tẹ ọhun ati Oloogbe Mala, adugbo kan ti wọn n pe ni Uro, niluu Ajọwa Akoko, lawọn mejeeji ti jọ ṣe kekere, nibẹ naa ni wọn si jọ dagba si.
Ọkan ninu awọn ero inu ọkọ to raaye sa asala lasiko tawọn agbebọn ọhun ṣe akọlu si ọkọ Mala nigba to n pada bọ lati Abuja lọjọ iṣẹlẹ ọhun ni wọn lo da oju afurasi ti a ko ti i morukọ rẹ naa mọ, oun lo si lọọ fi ohun to ri to awọn araalu leti, leyii to ṣokunfa bi wọn ṣe lọọ mu un lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Ohun ta a gbọ ni pe ọkunrin tọwọ tẹ ọhun ti fẹnu ara rẹ jẹwọ ipa to ko lori iku ọrẹ rẹ fawọn to fọrọ wa a lẹnu wo.
Gbogbo akitiyan awọn ọlọpaa Oke-Agbe Akoko, eyi ti ọga ọlọpaa teṣan ọhun, Paulinus Unnah ko sodi lati ri afurasi naa gba lọwọ awọn ero ni wọn ni ko so eeso rere pẹlu bi wọn ko ṣe fun awọn agbofinro naa laaye ki wọn sun mọ ibi to wa.
Ohun ti a ko ti i le sọ lasiko ta a n ko iroyin yii jọ lọwọ ni boya wọn pada ri ọkunrin naa gbe lọ si teṣan tabi bẹẹ kọ.
Iroyin mi ta a tun gbọ ni pe awọn arinrin-ajo bii meje lawọn ọlọpaa tu silẹ lọwọ awọn ajinigbe lagbegbe Akoko lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, kan naa.
Awọn arinrin-ajo ọhun ti wọn n bọ lati ipinlẹ Gombe ni wọn lawọn agbebọn da lọna lagbegbe Akunu-Ayere Akoko, lọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii, ti wọn si ko wọn wọnu igbo lọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmi Ọdunlami, ni bi wọn ṣe n fi iṣẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa teṣan Ikarẹ Akoko leti ni wọn ti bẹrẹ igbesẹ lori ati ṣawari awọn ti wọn ji gbe naa lọnakọna.
Igbiyanju awọn ẹṣọ alaabo ọhun lo ni o so eeso rere pẹlu bi wọn ṣe ri awọn mejeeje ti wọn ji gbe gba pada lọwọ awọn to ji wọn gbe, ti awọn eeyan naa si ti bẹrẹ irinajo wọn lakọtun.

Leave a Reply