PDP ti gba pe ilẹ Hausa la ti maa mu oludije funpo aarẹ– Babangida Aliyu

Faith Adebọla

 Gomina ipinlẹ Niger tẹlẹ ri, Ọmọwe Babangida Aliyu, to tun jẹ eekan ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ti ṣiṣọ loju eegun, o ni agbegbe Oke-Ọya ni ẹgbẹ naa yoo ti mu ondije funpo aarẹ ninu eto idibo ọdun 2023, o lawọn ti fohun ṣọkan lori ẹ.

Aliyu sọrọ yii lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, lasiko to n ṣepade pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ Atiku Support Organisation (ASO), ẹgbẹ ti wọn fi n ko awọn alatilẹyin jọ fun igbakeji aarẹ tẹlẹ ri, Abubakar Atiku, lati dije dupo aarẹ lọdun 2023 ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.

Lẹyin toun ati awọn oloye ẹgbẹ naa ti kọkọ tilẹkun mọri ṣepade, Aliyu ba awọn oniroyin sọrọ, o ni:

“Ninu eto ta a fẹnu ko le lori nipa agbegbe ti awọn oloye ẹgbẹ ati awọn ondije dupo pataki lasiko eto idibo gbogbogboo yoo ti wa, a ti gba lati jẹ ki aarẹ wa lati agbegbe Ariwa, ṣugbọn lakọọlẹ, a fun gbogbo eeyan to ba fẹẹ dupo aarẹ lanfaani lati ṣe bẹẹ, lai ka agbegbe yoowu ko ti wa si.

“O le jẹ Ila-Oorun/Ariwa, tabi Iwọ-Oorun/Ariwa, o si le jẹ Aarin-gbungbun/Ariwa, mi o le sọ, ṣugbọn Oke-Ọya la ti maa mu aarẹ wa, ẹni ta a ba mu la maa gbaruku ti.”

Gomina tẹlẹri naa tun gboriyin fun ẹgbẹ to n ṣatilẹyin fun Atiku Abubakar yii, o ni ọlọgbọn eeyan ni wọn, bi wọn ṣe n lọ labẹlẹ, lai pariwo, lati ipinlẹ kan si ekeji, ti wọn si n de ọdọ awọn eekan eekan to yẹ lati wa atilẹyin fun ọga wọn, igbesẹ to daa gidi ni.

O ni inu oun dun pe gbogbo origun mẹrẹẹrin Naijiria ni wọn kari.
Ẹni to jẹ Oluṣekokaari apapọ fun ẹgbẹ ASO naa dupẹ lọwọ Babangida Aliyu, o lo wa ninu awọn igi lẹyin ọgba fun Alaaji Atiku Abubakar, ko si ṣẹṣẹ bẹrẹ, o lo ti pẹ tọkunrin naa ti n ṣatilẹyin fọga oun.

Leave a Reply