Saheed Oṣupa kawe gboye ni Yunifasiti Ibadan

Adefunkẹ Adebiyi

Ni bayii, bi wọn ba n pe awọn to kẹkọọ gboye ni yunifasiti, Ọba orin Saheed Akorede Okunọla tawọn eeyan mọ si Saheed Oṣupa naa ti di ọkan lara wọn. Idi ni pe oṣere Fuji ọmọ ilu Ibadan naa ti kawe gboye ninu imọ oṣelu ni Yunifasiti Ibadan.

Ọjọ kẹrin, oṣu kẹfa, ọdun 2016 ni, Oṣupa darapọ mọ wọn ni Yunifasiti Ibadan lati kẹkọọ nipa imọ oṣelu (Political Science). Bo ti n ba ẹkọ ọhun bọ ree ko too waa gba B.Sc ninu ẹkọ ọhun bayii.

Ki i ṣe pe ọkunrin onifuji yii n fi gbogbo igba ba wọn jokoo si kilaasi, ọna tawọn to ba n ṣiṣẹ ti wọn si tun n kawe n gba loun naa fi kẹkọọ yii, ohun to jẹ ko pẹ to asiko yii niyẹn.

Ajegunlẹ, l’Ekoo, l’Oṣupa ti bẹrẹ ileewe akakọọbẹrẹ, ni Saint Mary’s Primary School. Ileewe girama, Amuwo Ọdọfin, to wa ni Mile 2, lo si ti pari abala ẹkọ keji lọdun 1987.

1992 l’Oṣupa pari abala ẹkọ akọkọ ni Poli Ibadan, iyẹn National Diploma. Ẹkọ nipa iṣakoso okoowo lo kọ nigba naa ( Business Administration).

Bi ifẹ rẹ lati kẹkọọ si ti pọ to, ọkan ninu awọn akẹkọọ gboye tun ni ọkunrin yii ni American International College, ẹkọ nipa bi aye ṣe n lu jara wọn loṣere Fuji yii kọ nibẹ.

Gbogbo afẹnifẹre lo ti n ba Saridon Papa yọ lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kin-in-ni, ti iroyin ayọ naa ti gbode.

Leave a Reply