Faith Adebọla, Eko
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti buwọ lu abadofin kan lori iṣoro awọn ẹlẹgbẹ okunkun nipinlẹ Eko, abadofin naa si ti dofin bayii pe ki ẹnikẹni to ba jẹbi ṣiṣe ẹgbẹ okunkun nipinlẹ Eko lọọ fẹwọn ọdun mọkanlelogun jura.
Ninu ofin yii ni wọn ti ka ṣiṣe ẹgbẹ okunkun leewọ lorigun mẹrẹẹrin ipinlẹ Eko, ofin naa tun gbe ijiya ọdun mẹẹẹdogun kalẹ fẹnikẹni to ba mọ-ọn-mọ ṣe onigbọwọ fun ọmọ ẹgbẹ okunkun nipinlẹ ọhun.
Ọsan ọjọ Aje, Mọnde yii, ni gomina buwọ lu abadofin tawọn ile-igbimọ aṣofin ti fi sọwọ si i tẹlẹ, ibuwọlu naa lo sọ abadofin ọhun di ofin, o si ti bẹrẹ iṣẹ loju-ẹsẹ.
Ninu ofin tuntun yii, ẹwọn ọdun mọkanlelogun lo n duro de ẹnikẹni to ba ṣe ibura fun ẹnikan lati di ọmọ ẹgbẹ okunkun, ati ẹni to gba lati ṣe iru ibura bẹẹ, ẹnikẹni to ba lọ, tabi wa nibi ti wọn ti n ṣe ibura ọhun, ẹnikẹni to ba pesẹ sibi ipade ẹgbẹ okunkun eyikeyii, tabi ẹnikẹni to ba parọwa pe kẹlomi-in waa ṣe ẹgbẹ okunkun.
Ẹwọn ọdun mẹẹẹdogun ni ofin naa ni ki wọn sọ ẹnikẹni to ba halẹ mọ ẹlomi-in lati ṣe ẹgbẹ okunkun si.
Ẹwọn ọdun meji gbako ni wọn lo n duro de ọmọleewe eyikeyii to ba jẹbi ṣiṣe ẹgbẹ okunkun ninu ọgba ileewe rẹ.