Ti ẹni to fẹẹ dupo aarẹ ẹgbẹ wa ba fi le wa lati Ariwa, a maa ṣeto idibo abẹle mi-in ni – Bọde George

Faith Adebọla

Dugbẹdugbẹ to n fi loke tẹnikan o ti i mọ ibi to maa ja si lọrọ yiyan agbegbe ibi ti aarẹ Naijiria ti yoo gbapo lọwọ Muhammadu Buhari yoo ti jade wa. Idi ni pe gbajugbaja oloṣelu ilu Eko, to tun jẹ agba ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Oloye Ọlabọde George, ti sọ pe ẹgbẹ PDP maa tun ibo abẹle mi-in ṣe ni to ba fi le jẹ pe eeyan agbegbe Oke-Ọya lo wọle sipo lati dupo aarẹ, tori iyan maa di atungun niyẹn, ọbẹ si maa di atunse.

George, to ti figba kan jẹ Igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu naa, sọ fakọroyin Independent lọjọ Aiku, Sannde yii, pe oun o fara mọ bi PDP ṣe fẹẹ ṣi anfaani ondupo fun ipo aarẹ silẹ fun gbogbo eeyan, lai ka agbegbe ti tọhun ba ti wa si, o lohun ti wọn fi le pin ipo alaga ẹgbẹ si agbegbe Ariwa orileede yii, wọn gbọdọ pin ipo ondije aarẹ si agbegbe Guusu ni.

O ni: “Ti ondije fun ipo aarẹ ba fi le yọju lati Ariwa, a maa ni lati pada lọọ tun eto idibo abẹle mi-in ṣe ni, ka tun awọn ọmọ-oye ẹgbẹ pin sawọn agbegbe mi-in. Ipo awọn oloye ẹgbẹ ti wọn wa lati Ariwa tẹlẹ ka too ṣe apero apapọ to waye nibẹrẹ oṣu kọkanla yii ti bọ si Guusu bayii, ti Guusu naa si ti bọ si Ariwa. Aarẹ ati alaga ẹgbẹ ko le wa lati agbegbe kan naa. To ba fi jẹ Ariwa ni ondije dupo aarẹ ti jade, a maa tun ṣeto apero apapọ ẹgbẹ mi-in ni.

Alaga PDP tuntun yii, Sẹnetọ Iyorchia Ayu, ki i ṣe ọjẹ wẹwẹ oloṣelu, o mọ tifun-tẹdọ bi nnkan ṣe n lọ ninu ẹgbẹ wa, gbogbo ilana ati eto bi a ti ṣe maa n ṣe e ti ye e yekeyeke.

A o kan ki i yan alaga ẹgbẹ ṣakala, a gbọdọ dibo yan an ni apero apapọ ni, tori nnkan ti ofin wa sọ niyẹn, a o si gbọdọ dẹjaa, kọrọ ma tun di wahala nile-ẹjọ, alaga o gbọdọ gba ọna awuruju kan wa. Ti a o ba ṣe atunyan daadaa, ajọ INEC le lawọn o fara mọ ẹni ti wọn yan.

Leave a Reply