Tirela lọọ ya ba awọn obinrin oniṣowo mẹwaa ninu ọja, lo ba tẹ wọn pa

A-gbọ-fọwọ-gbari-mu ni iku ojiji to ṣe kongẹ awọn obinrin oniṣowo mẹwaa ti tirela akoyọyọ pa nifọnna ifọnṣu lọsan-an ọjọ Abamẹta, Satide yii, ibi tawọn obinrin naa ti n ṣe karakata wọn lọwọ ni tirela naa ti ya lọ ba wọn.

Yatọ sawọn mẹwaa to doloogbe loju-ẹsẹ, a gbọ pe eeyan bii marundinlogoji ni wọn sare gbe digbadigba lọ sọsibitu, ti wọn ṣi wa lẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun latari bi wọn ṣe fara pa yannayanna ninu ijamba ọhun.

Ọja nla kan ti wọn n pe ni Ọja Nkwommiri, nijọba ibilẹ Nwangele, nipinlẹ Imo, niṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọgbẹni Ọlando Ikeokwu, ṣalaye pe o ṣee ṣe ko jẹ niṣe ni ọkọ ajagbe naa padanu bireeki ẹ, ati pe ere asapajude lo sa de agbegbe naa.

Olando ni ohun tawọn gbọ lẹnu awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni pe ojiji ni tirela naa yọ sawọn obinrin ti wọn n na ọja wọn jẹẹjẹ, wọn ni dẹrẹba naa du ọkọ ọhun rabaraba, ṣugbọn ijanu ọkọ naa ko ṣiṣẹ, niṣe lo kọ lu awọn oniṣowo naa, o si gori wọn, ko too lọọ ṣubu le awọn mi-in mọlẹ, to si da okuta ẹyin rẹ le wọn lori.

Wọn ni ko sẹnikẹni to mọ bi dẹrẹba ọkọ naa ṣe poora mọ wọn loju kawọn ero too debẹ.

Ọlando ni wọn ti ko oku awọn to doloogbe lọ si mọṣuari kan, awọn yoo si ṣewadii siwaju lori iṣẹlẹ ọhun.

Leave a Reply