Tirela tẹ ọlọkada atero to gbe pa l’Abẹokuta 

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ Iṣẹgun,Tusidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Keji yii, ni ijamba mọto kan ṣẹlẹ nikorita Moore, nitosi Car wash, l’Abẹokuta, ti ọlọkada atero to gbe sẹyin pade iku ojiji, tirela kan to n sare bọ lo tẹ wọn pa.Awọn tiṣẹlẹ yii ṣoju wọn ṣalaye pe ọlọkada naa n gbiyanju lati kọja nibi ikorita naa ni, ti tirela fi n ja bọ, to si run oun at’ẹni to gbe sẹyin pa.Bi eyi ṣe ṣẹlẹ lawọn eeyan fibinu dana sun tirela to tẹ wọn pa naa, awọn mọto mi-in ti ọrọ ọhun ko kan paapaa fara gba ninu ẹ. Ṣugbọn dẹrẹba to wa tirela to paayan meji naa sa lọ raurau.DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, fìdi iṣẹlẹ yii mulẹ. O lawọn ti bẹrẹ iwadii lori ẹ.

Leave a Reply