Wọn gun ọkunrin yii lọbẹ ni o, nile idibo l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọlọrun nikan lo le la ẹmi ọmọkunrin kan ti wọn gun lọbẹ niluu Akurẹ lasiko ti eto idibo sipo gomina to waye niluu Ondo n lọ lọwọ.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ti gbe ọmọkunrin naa digbadigba lọ sọsibitu, awọn to ri ẹjẹ to n da lara rẹ sọ fun akọroyin wa pe Ọlọrun nikan lo lo le ko o yọ. Wọọdu kẹrin, Ile idibo 002, ni  Ijomu, to wa ni Guusu Akurẹ ni iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.

Awọn janduku kan ni wọn deede kọlu ọmọkunrin naa lasiko to fẹẹ dibo gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Lẹyin ọdun mẹta ti tẹnanti tilẹkun ile pa, adajọ ni ki lanlọọdu lọọ ja a n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Ilọrin paṣẹ ki …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: