Faith Adebọla, Eko
Awọn ọdọ tinu n bi ti tun sọ ina si Sẹkiteriati Ibẹju-Lẹkki, to wa Lerekuṣu Eko. Ile ati mọto to wa ninu ọgba naa ti n jona bayii.
Eyi ko ṣẹyin bawọn ọdọ yii ṣe n binu latari bawọn ṣọja kan ṣe lọọ yinbọn pa lara wọn to n ṣewọde ta ko SARS lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lagbegbe Lekki, nipinlẹ Eko.
Wọn ni niṣe lawọn ọdọ naa ya bo Sẹkiteriati ọhun pẹlu epo bẹntiroolu, lẹye-o-sọka ni wọn si dana si gbogbo dukia ati ile to wa ninu ọgba naa.
Lalaalaa ni ina ṣi n jo nibẹ lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.