Ọpọ eeyan fara gbọta ninu akọlu to tun waye l’Ọwọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọpọ eeyan la gbọ pe wọn fara gbọta ninu akọlu tuntun mi-in tawọn agbebọn kan tun ṣe niluu Ọwọ lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Akọlu yii lo waye lẹyin bii osu kan ataabọ tawọn agbebọn paayan rẹpẹtẹ ninu ṣọọsi Katoliiki Francis Mimọ to wa lagbegbe Ọwaluwa, niluu Ọwọ yii kan naa.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, awọn agbebọn ọhun ni wọn deede da ibọn bolẹ, ti wọn si tun n yin ado oloro ni ileesẹ oju-ọna kan to wa nitosi adugbo Fọlahanmi, l’Ọwọ, lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ninu eyi tawọn eeyan kan ti fara pa yannayanna.

Ibi akọlu tuntun naa ni wọn ni ko fi bẹẹ jinna rara si ọgba ileewe kan, nibi ti wọn ti n ṣe idanilẹkọọ lọwọ fawọn ẹṣọ Amọtẹkun tuntun bii irinwo (400), eyi ti wọn ṣẹṣẹ fẹẹ gba ṣiṣẹ.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami, ni awọn eeyan mẹta loun gbọ pe wọn ṣi fara pa ninu iṣẹlẹ naa.

Ọdunlami ni oun ko ti i le sọ ni pato boya  awọn afẹmiṣofo tabi awọn agbebọn lo waa ṣe akọlu naa.

Alakooso ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ ninu ọrọ tirẹ ni loju-ẹsẹ ti oun gbọ nipa iṣẹlẹ to waye ọhun loun ti ṣabẹwo sibẹ lati foju ara oun ri ohun to ṣẹlẹ gan-an.

O ni awọn ọlọdẹ meji to n ṣọ ileeṣẹ ọhun nikan ni wọn fara pa lasiko tawọn agbebọn naa n yinbọn soke kikankikan.

Bakan naa lo ni awọn janduku ọhun tun fi ibọn fọ gilaasi katapila nla kan to wa ninu ileeṣẹ oju ọna ọhun. Awọn ti wọn fara pa naa lo ni wọn ti gbe lọ si ọsibitu kiakia fun itọju.

Oludamọran fun gomina lori eto aabo ọhun rọ awọn araalu, paapaa awọn eeyan ilu Ọwọ lati fọkan ara wọn balẹ, ki olukuluku si maa ba ka-ta-ka-ra wọn lọ lai foya, nitori pe gbogbo igbesẹ to yẹ lawọn ẹṣọ alaabo ti gbe lati bojuto iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply