Ademọla Adeleke jawe olubori nibi idibo Ọṣun

Florence Babaṣọla

Ademọla Adeleke to dije lorukọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun lo jawe olubori nibi eto idibo to waye ni ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ to kọja yii.

Ijọba ibilẹ mẹtadinlogun ni oloṣelu ọmọ bibi ilu Edẹ naa ti rọwọ mu ninu ijọba ibilẹ ọgbọn to wa nipibnlẹ naa, nigba ti Gomina Oyetọla ti ẹgbẹ APC rọwọ mu ni ijọba ibilẹ mẹtala pere.

Lẹyin ti wọn ka ibo tan, ibo irinwo o le mẹta ati diẹ (403, 371) ni Adeleke to ṣoju ẹgbẹ PDP ni, nigba ti Oyetọla to ṣoju APC ni ibo ọrinlelọọọdunrun o din marun-un (375, 027).

Leave a Reply