Ibọn ọlọpaa ba ole loju ija ni Ṣagamu, lo ba ku patapata

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Laaarọ kutu ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu keje yii, awọn ikọ adigunjale kan n ṣọṣẹ loju ọna Ṣagamu si Ijẹbu-Ode, ni wọn ba bọ sọwọ awọn ọlọpaa Odogbolu to n kọja, nigba naa ni wọn yinbọn pa ọkan ninu awọn adigunjale naa.

Ki i ṣe pe gende to doloogbe naa ku lẹsẹkẹsẹ ti ibọn ba a, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ pe nigba ti wọn n gbe e lọ sọsibitu lo dagbere faye.

Abimbọla ṣalaye pe awọn adigunjale naa to meje, niṣe ni wọn di oju ọna pa lagbegbe Southwestern University, wọn si n da awọn eeyan to n kọja lọna, wọn n gba tọwọ wọn pẹlu ibọn.

Nibi ti wọn ti n ṣe bẹẹ lọwọ ni olobo ti ta awọn ọlọpaa Odogbolu to n yi agbegbe naa ka, pẹlu awọn ṣọja kan to kọwọọrin pẹlu wọn, ni wọn ba lọọ koju awọn adigunjale ọhun.

Gẹgẹ bi Oyeyẹmi ṣe wi, o ni bi wọn ṣe ri awọn agbofinro naa ni awọn ole yii doju ija kọ wọn, eyi ti wọn si jọ fi yinbọn mọra wọn ko din niṣẹju marundinlaaadọta. Nibi ti wọn ti n yinbọn ọhun lo ti ba eyi to ku yii, awọn yooku rẹ gbe ọta ibọn sa lọ. Njẹ ki wọn si gbe eyi tibọn ba lọ sọsibitu, oju ọna ni ọlọjọ ti de ba a.

Ṣa, awọn ọlọpaa ni bi ẹnikẹni ba kofiri ẹni to n gbe ọta ibọn kiri, ki wọn fi to ileeṣẹ ọlọpaa to ba wa nitosi leti, nitori o ṣee ṣe ko jẹ lara awọn ole tibọn ba naa ni.

Leave a Reply