L’Ọṣun, adajọ ju babalawo sẹwọn, wọn lo lu ẹnikan ni jibiti owo nla

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Ileṣa ti paṣẹ pe ki babalawo kan, Kehinde Ọla, lọọ naju lọgba ẹwọn ilu Ileṣa lori ẹsun pe o lu ẹnikan ni jibiti ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin Naira.

Ọla, ẹni ọdun mejilelogun, lo gbowo lọwọ Adeṣọji Ọmọlẹwa, ẹni ti iya rẹ wa lori idubulẹ aisan, to si ṣeleri pe oun yoo mu iya naa larada.

Agbefọba to n ṣe ẹjọ naa, Inspẹkitọ Jimoh Mufutau, sọ fun adajọ pe ninu oṣu Keji, ọdun yii, ni olujẹjọ gba owo naa lọwọ Adesọji lagbegbe Iyemogun, niluu Ileṣa.

O ni bo ṣe gba a tan ni ọrọ yipada, ara iya ko ya gẹgẹ bo ṣe ṣeleri, bẹẹ ni ko si da owo pada nigba ti ko ri iwosan ṣe.

Mufutau fi kun ọrọ rẹ pe iwa ti olujẹjọ hu naa lodi si ofin, o si nijiya labẹ ipin okoodinnirinwo o din mẹtadinlogun, irinwo o din mẹwaa ati okoolenirinwo o din ẹyọ kan abala ikẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun.

Nigba ti wọn beere boya o jẹbi ẹsun jibiti lilu ati sisọ nnkan oni nnkan di tẹni ti wọn fi kan an, o ni oun ko jẹbi.

Ninu idajọ rẹ, Majisreeti O. A. Ọlọyade sọ pe oun ko le fun olujẹjọ ni beeli, o si paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa maa gbe e lọ si ọgba ẹwọn ilu Ileṣa titi digba ti wọn yoo gbẹjọ lori ọrọ beeli rẹ.

Ọlọyade sun igbẹjọ si ọjọ kẹta, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.

Leave a Reply