Mo mọ Tinubu daadaa, ẹni ọdun mẹrindinlaaadọrun ni, ko le dari Naijiria -Tee Mac 

Monisọla Saka

Gbajugbaja ọkunrin to maa n fọ fere, to tun figba kan jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn olorin nilẹ Naijiria, Tee Mac Omatshola Iseli, ti ki awọn ọmọ orilẹ-ede yii nilọ lati ma ṣe dibo yan oludije dupo aarẹ lẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, ninu ibo gbogbogboo to n bọ. O ni ọjọ ori rẹ ju iye to pe ara ẹ lọ, ko si le tukọ ilẹ yii pẹlu arugbo ara naa.

Tee Mac ṣalaye pe àna oun ni Jagaban, bẹẹ lo fi kun un pe ohun gbogbo nipa ọkunrin to ti ṣe gomina Eko ri yii, to si tun fẹẹ ṣe aarẹ ilẹ wa bayii lo ṣokunkun, ti wọn si n ṣe e ni bonkẹle, nipasẹ bẹẹ, ko yẹ lẹni to yẹ ki wọn gbe iṣẹ idari Naijiria le lọwọ.

O ni titi di asiko yii ni ọrọ ọjọ ori Tinubu ati ọna to gba ri owo rẹ ṣi jẹ adiitu.

Tee Mac ni, ‘Ẹni to ba wu onikaluku lo le dibo fun o, ṣugbọn ẹni ti ori rẹ ba pe daadaa yoo beere lọwọ ara rẹ  njẹ ẹni to yẹ ni mo fẹẹ yan yii? Ṣe ọkunrin yii kun oju oṣuwọn? Ṣe olododo eeyan ni? Ṣe o sọ ootọ fun wa nipa ọjọ ori rẹ, ibi to ti n bọ ati bo ṣe rowo rẹ? Njẹ ọkunrin yii ni ilera pipe ni ẹni ọdun mẹrindinlaaadọrin (86years) to jẹ lati dari orileede yii?’

Ọkunrin yii ni ọmọ ẹgbọn oun ni iyawo rẹ, Olurẹmi Tinubu. O ni tẹgbọn-taburo ni iya oun to jẹ ẹya Itsekiri ati iya obinrin yii toun naa jẹ ẹya Itsekiri. O fi kun un pe o ti le logoji ọdun ti oun ti mọ Tinubu, ati pe oun loun ṣeto bi o ṣe gbe ile ọkọ iya oun, (Sir Mobọlaji Bank-Anthony), niluu London, nigba to lọọ ṣe atipo nibẹ.

‘Nigba ti o ta Buhari fun wa lọdun 2015 ni mo dawọ atilẹyin mi fun un duro, ti mi o si de ile rẹ mọ.’ O ni pelu bi oun ṣe jẹ ana rẹ to yii, oun ko le ṣatilẹyin fun un lati wọle sipo aarẹ. O waa gba awọn ọmọ Naijiria niyanju pe ki wọn ma ṣe dibo fun un, nitori ko kun oju oṣuwọn  lati di aarẹ Naijiria.

Leave a Reply