Naijiria n ṣaisan, ẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun lo wa -Imaamu Agba Fasiti Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ko si ẹni ta a le jẹrii pe yoo ṣe daadaa ninu gbogbo awọn to n dupo oṣelu lorileede yii, Ọlọrun funra Ẹ nikan lo le yan ẹni to ba wa U fun wa.

Imaamu agba University of Ibadan (UI), Ọjọgbọn Muftau Oloyede Abdul-Rahman, lo sọrọ yii fawọn oniroyin ni kete to kirun ọdun Ileya ọdun yii fawọn Musulumi ni yidi to wa ninu ọgba fasiti naa lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹsan-an, oṣu Keje, ọdun 2022 yii.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “mo nigbagbọ kan pe ta a ba maa dibo yan eeyan sipo aarẹ orileede yii, a nilo iriri ati jijẹ ọmọluabi, ṣugbọn gbogbo ẹ lo ti ja wa ni tanmọ-ọn bayii, ẹni ta a yan nitori pe o ni iriri, ti ki i sí í kowo jẹ, ti ja wa kulẹ.

“Nnkan ti Daru mọ awọn eeyan yii (ijọba) loju, ko ye awọn paapaa mọ. Adura nikan la nilo.

“Naijiria n ṣaisan, ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun lo wa, o ti fẹẹ yoro patapata. Ohun ta a nilo bayii ni adura pe ki Ọlọrun ma jẹ ki Naijiria parẹ.

“Ko si bi awọn oloṣelu ko ṣe ni i maa ṣeleri ti wọn ko ni i mu ṣẹ nitori apo ara wọn nikan ni wọn n ja fun. Iyẹn la ṣe ni lati bẹ Ọlọrun lati funra rẹ yan adari gidi fun wa”.

Ọjọgbọn Abdul-Rahman bu ẹnu atẹ lu bi apa ijọba ko ṣe ka ọrọ eto aabo ilẹ yii, o ni “ki lo de ti apa awọn agbofinro ati ologun wa ko ka ọrọ eto aabo mọ. Sebi ijọba n ya owo nla nla sọtọ fun eto aabo ninu eto iṣuna orile-ede yii, ki lo de ti wọn ko na owo ọhun sori eto aabo?’’

O waa ṣapejuwe awọn to n kọ lu ṣọọṣi, ti wọn n ji awọn olori ijọ ẹlẹsin Kirisitẹni gbe kiri gẹgẹ bii ọta Ọlọrun.

O ni “Ọlọrun sọ ọ ninu Kuraani pe ẹnikẹni to ba paayan lọna ti ko bofin mu, Oun Ọlọrun ko ni i gba adura iru ẹni bẹẹ.

“Bi ẹnikan ba wa n paayan kiri gẹgẹ bi wọn ṣe n ṣe ni Naijiria yii, ọta Ọlọrun ni iru ẹni bẹẹ. Ẹ ẹ si ri i pe iroyin ti fi ye wa pe awọn to paayan si ṣọọṣi niluu Ọwọ laipẹ yii, lati orileede mi-in ni wọn ti wa. Iyẹn lo fi ye wa pe ija ti wọn n ja yii ki i ṣe nitori ẹsin, wọn fẹẹ gba ilẹ wa mọ wa lọwọ ni”.

Leave a Reply