Ọmọọba Saka Adelọla Matẹmilọla di Olowu tuntun

Gbenga Amos, Abokuta

Ọrọ yiyan ọba tuntun sori apere Olowu tilẹ Owu ti ditan wayi, wọn ti kede Ọmọọba Saka Matẹmilọla gẹgẹ bii ẹni ti yoo gori itẹ awọn baba nla rẹ, ti yoo si di Olowu kẹrinla, nijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta, nipinlẹ Ogun.

Ikede yii wa ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin, fi lede l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keje yii, lorukọ ọga rẹ, lẹyin ipade igbimọ alakooso ipinlẹ naa to waye lalẹ ọjọ Aje, Mọnde ọsẹ kan naa.

Iyansipo yii ni yoo di alafo to ṣi silẹ lori itẹ naa lati oṣu Kejila, ọdun 2021, nigba ti Ọba Adegboyega Dosunmu waja, to lọọ darapọ mọ awọn baba nla rẹ.

Titi di asiko iyansipo rẹ yii, Matẹmilọla ni ọga agba ileeṣẹ Ankor Pointe Integrated, o si jẹ ọmọ-ẹgbẹ Light House Muslim Community, lagbegbe Lẹkki, nipinlẹ Eko.

Ọmọ bibi idile Matẹmilọla ni agboole Sọkẹ, ni Owu, Abẹokuta, l’ọmọọba yii, o kawe gboye ọmọwe (Ph.D) ninu imọ ijinlẹ mẹkaniiki, lati Fasiti Cambridge, lorileede United Kingdom, bẹẹ lo wa lara awọn oludanilẹkọọ ninu imọ nipa iwakusa ati epo rọbi ni Fasiti Port-Harcourt, nipinlẹ Rivers.

Ṣaaju asiko yii ni wọn ti mọ Ọmọọba Matẹmilọla bii ẹni mowo ni ilu abinibi rẹ fun ọpọ nnkan amayedẹrun to n pese faraalu bii kanga igbalode, iranwọ owo oṣooṣu fawọn alaini, iranwo lori eto ilera ati eto ẹkọ.

Ọjọ kẹrin, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni Saka yoo dẹni ọdun mọkandinlọgọta, tori ọdun 1964 ni wọn bi i.

Leave a Reply