Portable ti fẹnu kọ o, ọga ọlọpaa patapata ti paṣẹ ki wọn mu un

Faith Adebọla

Ko jọ pe wọn ru ẹbọ olubọbọ tiribọ, baba ẹnu, fun gbajugbaja onkọrin taka-sufee Zah Zuh Zeh to gbajumọ laarin awọn ọdọ iwoyi, Ọgbẹni Habeeb Okikiọla, tawọn eeyan mọ si Portable. Ọga patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa l’Abuja, Usman Alkali Baba, ti paṣẹ pe ki wọn fi pampẹ ofin gbe onkọrin naa nibikibi ti wọn ba ti pade, wọn lo gbọdọ waa ṣalaye ajọṣe ẹ pẹlu awọn ẹlẹgbẹ okunkun fun ijọba.

Atẹjade kan lati ọwọ Alukoro apapọ funleeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejọbi, to fi lede lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlogun, oṣu Keje yii, lo fidi ọrọ mulẹ.

Ṣaaju ni fidio kan ti n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara lọjọ naa, ori ikanni Portable lo gbe fidio naa si, nibẹ ni onkọrin naa ti n ṣe fọnte, to n fọwọ gbaya gẹgẹ bii iṣe rẹ, o ni: “O jẹ la eti ẹ ko o gbọ mi, ẹ ẹn, ṣo o ti gbọ nipa awọn Ajah bọis, ati awọn One Million bọis, emi lọga wọn, emi ni mo da a silẹ, lọọ beere lọwọ Sammy Larry.”

Bo tilẹ jẹ pe o ti pa fidio naa rẹ kuro lori ikanni rẹ, ọpọ eeyan ni ọrọ ti Portable sọ yii ya lẹnu, tori awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn ṣoro bii agbọn laarin lọdun 2021 nipinlẹ Eko ati Ogun ni awọn ẹgbẹ mejeeji to darukọ yii.

Atẹjade naa ka lapa kan pe: “Latari bi Habeeb Okikiọla, ti inagijẹ rẹ n jẹ Portable, ṣe sọ ninu fidio to n ja ranyin kan pe oun loun da ẹgbẹ okunkun One Million Boys to ko ipaya ba awọn olugbe Eko silẹ, Ọga agba patapata ti paṣẹ ki wọn ṣewadii ọrọ ti olorin naa sọ, ki wọn si foju rẹ bale-ẹjọ.

“Aṣẹ yii jẹ ara isapa ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣawari gbogbo awọn amookunṣika, ati awọn baba isalẹ wọn, ki wọn le hu wọn tigbongbo-tigbongbo, ki alaafia si le jọba niluu.”

O fẹrẹ jẹ pe latigba ti onkọrin naa ti gbe awo Zah Zuh Zeh rẹ jade, eyi to sọ ọ di olokiki, boya ni oṣu kan yoo kọja ti awuyewuye kan ko ni i bẹ silẹ nipa iwakiwa tabi ọrọkọrọ ti Portable n sọ.

Tẹ o ba gbagbe, ogunjọ, oṣu Kẹfa, to kọja yii, ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun kede pe awọn n wa olorin naa fun bo ṣe fiya jẹ gende kan, to ni kawọn ẹmẹwa oun lu ẹni ẹlẹni lalubami, eyi ti wọn tori ẹ n wa a.

Bakan naa lawọn eeyan ṣi n sọrọ buruku si Portable fun bo ṣe sare lọọ ki Ademọla Adeleke to gbegba oroke ninu eto idibo sipo gomina to waye l’Ọṣun, kuu oriire, gẹrẹ lẹyin to ṣalatilẹyin fun gomina ipinlẹ naa, Oyetọla Gboyega, to fidi rẹmi.

Ọpọ awọn araalu lo n sọ pe okiki ojiji ti Portable ni yii lo n yọ ọ lẹnu.

Leave a Reply