Faith Adebọla Ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria, Christian Association of Nigeria (CAN) , ti laago ikilọ setiigbọ awọn oloṣelu lasiko yii pe awọn o ni i fara mọ oludije dupo aarẹ to jẹ ẹlẹsin Musulumi to ba fi ẹlẹsin Musulumi bii tiẹ ṣe igbakeji, wọn lawọn o ni i …
Read More »Wakilu to purọ pe Boko Haram ti wọlu Imọsan loun fẹẹ fi ṣẹru ba araalu lasan ni
Gbenga Amos, Abẹokuta Erekere, ere egele ti ọkunrin yii, Wakilu Ogundairo, ṣe niluu Imọsan, Ijẹbu, nipinlẹ Ogun, ti sọ ọ dero ahamọ awọn ọlọpaa bayii o, afaimọ ni ere naa ko si ni i gbe e dewaju adajọ, nitori iwa to hu ọhun ko awọn ọlọpaa ati araalu si ṣibaṣibo …
Read More »Ileeṣẹ eto idajọ ti gba Onidaajọ Oloyede, obinrin tijọba Arẹgbẹṣọla da duro l’Ọṣun, pada sẹnu iṣẹ
Florence Babaṣọla, Oṣogbo Odu ni Onidaajọ Ọlamide Oloyede, obinrin adajọ kan to kọ lẹta sijọba Gomina Arẹgbẹṣọla lọdun 2016 lori iya to n jẹ awọn oṣiṣẹ ijọba atawọn oṣiṣẹ-fẹyinti, ki i ṣe aimọ foloko. Gbogbo agbaye lo mọ nigba naa pe wọn da a duro lẹnu iṣẹ adajọ lẹyin to …
Read More »Adajọ ti ni ki wọn yẹgi fawọn Fulani tọwọ tẹ lori iku ọmọ Baba Faṣọranti
Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ Adajọ Ile-ẹjọ giga keje to wa l’Akurẹ, Onidaajọ Williams Ọlamide, ti dajọ iku fun mẹta ninu awọn ọdaran tọwọ tẹ lori ọrọ iku Funkẹ Arakunrin, ọmọ Oloye Reuben Faṣọranti, ti awọn agbebọn kan yinbọn pa loju ọna Marosẹ Ọrẹ si Ijẹbu-Ode, lọjọ kejila, ọsu Kẹje, ọdun 2019, …
Read More »Dọlapọ, iyawo Ọṣinbajo ki ọkọ rẹ: Ọmọluabi ni ọ, iwuri nla lo jẹ fun mi
Jọkẹ Amọri Iyawo Igbakeji Aarẹ orileede yii, Dọlapọ Ọṣinbajo, ti ki ọkọ rẹ, Yẹmi Ọṣinbajo, lẹyin to padanu anfaani lati ṣoju ẹgbẹ APC gẹgẹ bii oludije funpo aarẹ ti yoo waye lọdun to n bọ. Ninu ọrọ to kọ sori Instagraamu rẹ nipa ọkọ rẹ, Dọlapọ ni, ‘‘Oluleke, Ọmọluabi, Ọmọ …
Read More »Ẹgbẹ Afẹnifẹre ṣabẹwo ibanikẹdun si ilu Ọwọ
Jọkẹ Amọri Ẹgbẹ agba Yoruba nni, Afẹnifẹre, ti ṣabẹwo ibanikẹdun siluu Ọwọ, nipinlẹ Ondo, nibi ti wọn ti ki awọn eeyan ilu naa, Gomina Akeredolu, awọn ọmọ ijọ St Francis Catholic Church, ti iṣẹlẹ naa ti waye atawọn ti wọn fara pa ninu iṣẹlẹ naa, ti wọn si gbadura pe …
Read More »Nitori Tinubu, awọn ọmọ ita da ibọn bolẹ n’Ilẹ-Oluji, lawọn eeyan ba n sa kijokijo
Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ Ṣe lawọn eeyan n sa kijokijo pẹlu ibẹru nigba ti wọn n gbọ iro ibọn to n ro lakọlakọ laarin igboro Ilẹ-Oluji to jẹ ibujokoo ijọba ibilẹ Ilẹ-Oliji /Oke-Igbo, lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ ta a wa yii. Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, lojiji lawọn eeyan ilu ọhun …
Read More »Ajọ INEC kede ọjọ ti wọn gbọdọ kọ orukọ awọn oludije dupo ranṣẹ
Monisọla Saka Ajo eleto idibo ilẹ wa, INEC, ti kede pe ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹfa, ni awọn fun awọn oludije dupo aarẹ di ti wọn gbọdọ forukọ ẹni ti yoo ṣe igbakeji wọn silẹ. Ajọ yii ṣekilọ pe ẹrọ ayelujara ti wọn yoo lo lati fi orukọ awọn oludije dupo …
Read More »Tinubu ṣabẹwo si Yẹmi Ọṣinbajo
Adewumi Adegoke Ẹni ti wọn ṣẹṣẹ yan gẹgẹ bii oludije fun ẹgbẹ oṣelu APC funpo aarẹ, Aṣiwaju Tinubu, ti ṣabẹwo si Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ni ile ijọba, niluu Abuja, lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii. Lẹyin abẹwo to ṣe sọdọ Aarẹ Buhari lo ṣe abẹwo iyanu yii si ile …
Read More »Ọṣinbajo ranṣẹ ikini ku oriire si Bọla Tinubu
Jọkẹ Amọri Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ti ranṣẹ ikini ku oriire si Aṣiwaju Bọla Tinubu ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan gẹgẹ bii oludije funpo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC ninu ibo ọdun 2023. Ninu ọrọ ikini rẹ lo ti sọ pe, ‘‘Mo ki Aṣiwaju Bọla Tinubu fun …
Read More »Amaechi ki Tinubu ku oriire, o ṣeleri atilẹyin fun un
Jọkẹ Amọle Minisita feto irinna ọkọ tẹlẹ to tun ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Rivers, Rotimi Amaechi, ti ki Aṣiwaju Bọla Tinubu ku oriire bo ṣe yege ninu ibo abẹle APC to kọja yii lati dupo aarẹ ẹgbẹ naa, bẹẹ lo ṣeleri atilẹyin fun un lasiko idibo ọdun 2023. …
Read More »